Yorùbá Bibeli

2. Sam 3:18-26 Yorùbá Bibeli (YCE)

18. Njẹ, ẹ ṣe e: nitoriti Oluwa ti sọ fun Dafidi pe, Lati ọwọ́ Dafidi iranṣẹ mi li emi o gbà Israeli enia mi là kuro lọwọ awọn Filistini ati lọwọ gbogbo awọn ọta wọn.

19. Abneri si wi leti Benjamini: Abneri si lọ isọ leti Dafidi ni Hebroni gbogbo eyiti o dara loju Israeli, ati loju gbogbo ile Benjamini.

20. Abneri si tọ̀ Dafidi wá ni Hebroni, ogún ọmọkunrin si pẹlu rẹ̀. Dafidi si se ase fun Abneri ati fun awọn ọmọkunrin ti o wà pẹlu rẹ̀.

21. Abneri si wi fun Dafidi pe, Emi o dide, emi o si lọ, emi o si ko gbogbo Israeli jọ sọdọ ọba oluwa mi, nwọn o si ba ọ ṣe adehun, iwọ o si jọba gbogbo wọn bi ọkàn rẹ ti nfẹ. Dafidi si rán Abneri lọ; on si lọ li alafia.

22. Si wõ, awọn iranṣẹ Dafidi ati Joabu si ti ibi ilepa ẹgbẹ ogun kan bọ̀, nwọn si mu ikogun pupọ bọ̀; ṣugbọn Abneri ko si lọdọ Dafidi ni Hebroni; nitoriti on ti rán a lọ: on si ti lọ li alafia.

23. Nigbati Joabu ati gbogbo ogun ti o pẹlu rẹ̀ si de, nwọn si sọ fun Joabu pe, Abneri, ọmọ Neri ti tọ̀ ọba wá, on si ti rán a lọ, o si ti lọ li alafia.

24. Joabu si tọ̀ ọba wá, o si wipe, Kini iwọ ṣe nì? wõ, Abneri tọ̀ ọ wá; ehatiṣe ti iwọ si fi rán a lọ? on si ti lọ.

25. Iwọ mọ̀ Abneri ọmọ Neri, pe, o wá lati tàn ọ jẹ, ati lati mọ̀ ijadelọ rẹ, ati ibọsile rẹ, ati lati mọ̀ gbogbo eyi ti iwọ nṣe.

26. Nigbati Joabu si jade kuro lọdọ Dafidi, o si ran awọn iranṣẹ lepa Abneri, nwọn si pè e pada lati ibi kanga Sira: Dafidi kò si mọ̀.