Yorùbá Bibeli

2. Kor 13:4-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

4. Nitoripe a kàn a mọ agbelebu nipa ailera, ṣugbọn on wà lãye nipa agbara Ọlọrun. Nitori awa pẹlu jasi alailera ninu rẹ̀, ṣugbọn awa ó wà lãye pẹlu rẹ̀ nipa agbara Ọlọrun si nyin.

5. Ẹ mã wadi ara nyin, bi ẹnyin bá wà ninu igbagbọ́; ẹ mã dan ara nyin wò. Tabi ẹnyin tikaranyin kò mọ̀ ara nyin pe Jesu Kristi wà ninu nyin? afi bi ẹnyin ba jẹ awọn ti a tanù.

6. Ṣugbọn mo ni igbẹkẹle pe ẹnyin ó mọ̀ pe, awa kì iṣe awọn ti a tanù.

7. Njẹ awa ngbadura si Ọlọrun, ki ẹnyin ki o máṣe ibikibi kan; kì iṣe nitori ki awa ki o le fi ara hàn bi awọn ti a mọ̀ daju, ṣugbọn ki ẹnyin ki o le mã ṣe eyi ti o dara, bi awa tilẹ dabi awọn ti a tanù.

8. Nitori awa kò le ṣe ohun kan lodi si otitọ, bikoṣe fun otitọ.

9. Nitori awa nyọ̀, nigbati awa jẹ alailera, ti ẹnyin si jẹ alagbara: eyi li awa si ngbadura fun pẹlu, ani pipe nyin.

10. Nitori idi eyi, nigbati emi kò si, mo kọwe nkan wọnyi pe, nigbati mo ba de, ki emi ki o má bã lò ikannú, gẹgẹ bi aṣẹ ti Oluwa ti fifun mi fun idagbasoke, kì si iṣe fun iparun.

11. Li akotan, ará, odigboṣe. Ẹ jẹ pipé, ẹ tújuka, ẹ jẹ oninu kan, ẹ mã wà li alafia; Ọlọrun ifẹ ati ti alafia yio wà pẹlu nyin.

12. Ẹ fi ifẹnukonu mimọ́ kí ara nyin.

13. Gbogbo awọn enia mimọ́ kí nyin.

14. Ore-ọfẹ Jesu Kristi Oluwa, ati ifẹ Ọlọrun, ati ìdapọ ti Ẹmí Mimọ́, ki o wà pẹlu gbogbo nyin. Amin.