Yorùbá Bibeli

2. A. Ọba 6:10-17 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Ọba Israeli si ranṣẹ si ibẹ na ti enia Ọlọrun ti sọ fun u, ti o si ti kilọ fun u, o si gbà ara rẹ̀ nibẹ, kì iṣe nigbà kan tabi nigba meji.

11. Nitorina li ọkàn ọba Siria bajẹ gidigidi nitori nkan yi: o si pè awọn iranṣẹ rẹ̀, o si wi fun wọn pe, Ẹnyin kì yio ha fihan mi, tani ninu wa ti o nṣe ti ọba Israeli?

12. Ọkan ninu awọn iranṣẹ rẹ̀ si wipe, Kò si ẹnikan, oluwa mi, ọba; bikoṣe Eliṣa, woli ti mbẹ ni Israeli, ni nsọ fun ọba Israeli gbogbo ọ̀rọ ti iwọ nsọ ninu iyẹ̀wu rẹ.

13. On si wipe, Ẹ lọ iwò ibi ti on gbe wà, ki emi o le ranṣẹ lọ mu u wá. A si sọ fun u, wipe, Wò o, o wà ni Dotani.

14. Nitorina li o ṣe rán awọn ẹṣin ati kẹkẹ́ ati ogun nla sibẹ: nwọn si de li oru, nwọn si yi ilu na ka.

15. Nigbati iranṣẹ enia Ọlọrun na si dide ni kùtukutu ti o si jade lọ, wõ, ogun yi ilu na ka, ati ẹṣin ati kẹkẹ́. Iranṣẹ rẹ̀ si wi fun u pe, Yẽ! baba mi, awa o ti ṣe?

16. On si dahùn wipe, Má bẹ̀ru: nitori awọn ti o wà pẹlu wa, jù awọn ti o wà pẹlu wọn lọ.

17. Eliṣa si gbadura, o si wipe, Oluwa, emi bẹ̀ ọ, là a li oju, ki o lè riran. Oluwa si là oju ọdọmọkunrin na; on si riran: si wò o, òke na kún fun ẹṣin ati kẹkẹ́-iná yi Eliṣa ka.