Yorùbá Bibeli

2. A. Ọba 6:1-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. AWỌN ọmọ awọn woli wi fun Eliṣa pe, Sa wò o na, ibiti awa gbe njoko niwaju rẹ, o há jù fun wa.

2. Jẹ ki awa ki o lọ, awa bẹ̀ ọ, si Jordani, ki olukulùku wa ki o mu iti igi kọ̃kan wá, si jẹ ki awa ki o ṣe ibikan, ti awa o ma gbe. On si dahùn wipe, Ẹ mã lọ.

3. Ẹnikan si wipe, Ki o wu ọ, emi bẹ̀ ọ, lati ba awọn iranṣẹ rẹ lọ. On si dahùn pe, Emi o lọ.

4. Bẹ̃li o ba wọn lọ. Nigbati nwọn si de Jordani, nwọn ké igi.

5. O si ṣe, bi ẹnikan ti nké iti-igi, ãke yọ sinu omi: o si kigbe, o si wipe, Yẽ! oluwa mi, a tọrọ rẹ̀ ni.

6. Enia Ọlọrun si wipe, Nibo li o bọ́ si? O si fi ibẹ hàn a. On si ké igi kan, o si sọ́ ọ sinu rẹ̀; irin na si fó soke.

7. Nitorina o wipe, Mu u. On si nà ọwọ rẹ̀, o si mu u.

8. Nigbana ni ọba Siria mba Israeli jagun, o si ba awọn iranṣẹ rẹ̀ gbèro wipe, Ni ibi bayibayi ni ibùba mi yio gbe wà.

9. Enia Ọlọrun si ranṣẹ si ọba Israeli wipe Kiye sara, ki iwọ ki o máṣe kọja si ibi bayi; nitori nibẹ ni awọn ara Siria ba si.

10. Ọba Israeli si ranṣẹ si ibẹ na ti enia Ọlọrun ti sọ fun u, ti o si ti kilọ fun u, o si gbà ara rẹ̀ nibẹ, kì iṣe nigbà kan tabi nigba meji.

11. Nitorina li ọkàn ọba Siria bajẹ gidigidi nitori nkan yi: o si pè awọn iranṣẹ rẹ̀, o si wi fun wọn pe, Ẹnyin kì yio ha fihan mi, tani ninu wa ti o nṣe ti ọba Israeli?