Yorùbá Bibeli

2. A. Ọba 3:1-9 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. JEHORAMU, ọmọ Ahabu si bẹ̀rẹ si ijọba lori Israeli ni Samaria li ọdun kejidilogun Jehoṣafati, ọba Juda, o si jọba li ọdun mejila.

2. O si ṣe buburu li oju Oluwa; ṣugbọn kì iṣe bi baba rẹ̀, ati bi iya rẹ̀: nitoriti o mu ere Baali ti baba rẹ̀ ti ṣe kuro.

3. Ṣugbọn o fi ara mọ ẹ̀ṣẹ Jeroboamu, ọmọ Nebati, ti o mu Israeli dẹ̀ṣẹ; kò si lọ kuro ninu rẹ̀.

4. Meṣa, ọba Moabu si nsìn agutan, o si nsan ọkẹ marun ọdọ-agutan, ati ọkẹ marun àgbo irun fun ọba Israeli.

5. O si ṣe, nigbati Ahabu kú, ọba Moabu si ṣọ̀tẹ si ọba Israeli.

6. Jehoramu ọba si jade lọ kuro ni Samaria li akoko na, o si ka iye gbogbo Israeli.

7. O si lọ, o ranṣẹ si Jehoṣafati ọba Juda, wipe, Ọba Moabu ti ṣọ̀tẹ si mi: iwọ o ha bá mi lọ si Moabu lati jagun? On si wipe, Emi o gòke lọ: emi bi iwọ, enia mi bi enia rẹ, ati ẹṣin mi bi ẹṣin rẹ.

8. On si wipe, Ọ̀na wo li awa o gbà gòke lọ? On si dahùn wipe, Ọ̀na aginju Edomu.

9. Bẹ̃ni ọba Israeli lọ, ati ọba Juda, ati ọba Edomu: nigbati nwọn rìn àrinyika ijọ meje, omi kò si si nibẹ fun awọn ogun, ati fun ẹranko ti ntọ̀ wọn lẹhin.