Yorùbá Bibeli

2. A. Ọba 25:1-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. O si ṣe li ọdun kẹsan ijọba rẹ̀, li oṣù kẹwa, li ọjọ kẹwa oṣù, ni Nebukadnessari ọba Babeli de, on, ati gbogbo ogun rẹ̀, si Jerusalemu, o si dotì i; nwọn si mọdi tì i yika kiri.

2. A si dotì ilu na titi di ọdun ikọkanla Sedekiah.

3. Ati li ọjọ kẹsan oṣù kẹrin, iyàn mu gidigidi ni ilu, kò si si onjẹ fun awọn enia ilẹ na.

4. Ilu na si fọ́, gbogbo awọn ọkunrin ologun si gbà ọ̀na bodè lãrin odi meji, ti o wà leti ọgbà ọba, salọ li oru; (awọn ara Kaldea si yi ilu na kakiri;) ọba si ba ọ̀na pẹ̀tẹlẹ lọ.

5. Ogun awọn ara Kaldea si lepa ọba, nwọn si ba a ni pẹ̀tẹlẹ Jeriko: gbogbo ogun rẹ̀ si tuka kuro lọdọ rẹ̀.

6. Bẹ̃ni nwọn mu ọba, nwọn si mu u gòke lọ si ọdọ ọba Babeli ni Ribla; nwọn si sọ ọ̀rọ idajọ lori rẹ̀.

7. Nwọn si pa awọn ọmọ Sedekiah li oju rẹ̀, nwọn si fọ Sedekiah li oju, nwọn si fi ẹwọn idẹ dè e, nwọn si mu u lọ si Babeli.

8. Ati li oṣù karun, li ọjọ keje oṣù, ti iṣe ọdun ikọkandilogun Nebukadnessari ọba, ọba Babeli, ni Nebusaradani olori ẹ̀ṣọ, iranṣẹ ọba Babeli, wá si Jerusalemu: