Yorùbá Bibeli

2. A. Ọba 21:9-15 Yorùbá Bibeli (YCE)

9. Ṣugbọn nwọn kò feti silẹ: Manasse si tàn wọn lati ṣe buburu jù eyiti awọn orilẹ-ède ti Oluwa ti parun niwaju awọn ọmọ Israeli ti ṣe.

10. Oluwa si wi nipa awọn woli iranṣẹ rẹ̀ pe,

11. Nitoriti Manasse ọba Juda ti ṣe ohun-irira wọnyi, ti o si ti ṣe buburu jù gbogbo eyiti awọn ọmọ Amori ti ṣe, ti o ti wà ṣãju rẹ̀, ti o si mu ki Juda pẹlu ki o fi awọn ere rẹ̀ dẹṣẹ:

12. Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wi, Kiyesi i, emi nmu iru ibi bayi wá sori Jerusalemu ati Juda, ti ẹnikẹni ti o ba gbọ́ ọ, eti rẹ̀ mejeji yio ho.

13. Emi o si nà okùn Samaria lori Jerusalemu, ati òjé-idiwọ̀n ile Ahabu: emi o si nù Jerusalemu bi enia ti nnù awokoto, o nnù u, o si ndori rẹ̀ kodò.

14. Emi o si kọ̀ iyokù awọn ini mi silẹ, emi o si fi wọn le awọn ọ̀ta wọn lọwọ; nwọn o si di ikogun ati ijẹ fun gbogbo awọn ọ̀ta wọn.

15. Nitori nwọn ti ṣe eyiti o buru li oju mi, ti nwọn si ti mu mi binu, lati ọjọ ti awọn baba wọn ti jade kuro ni Egipti, ani titi di oni yi.