Yorùbá Bibeli

2. A. Ọba 19:33-37 Yorùbá Bibeli (YCE)

33. Ọna na ti o ba wá, ọkanna ni yio ba pada lọ, kì yio si wá si ilu yi, li Oluwa wi.

34. Nitori emi o da abò bò ilu yi, lati gbà a, nitori ti emi tikara mi, ati nitori ti Dafidi iranṣẹ mi.

35. O si ṣe li oru na ni angeli Oluwa jade lọ, o si pa ọkẹ́ mẹsan le ẹgbẹ̃dọgbọn enia ni ibùbo awọn ara Assiria: nigbati nwọn si dide ni kutukutu owurọ, kiyesi i, okú ni gbogbo wọn jasi.

36. Bẹ̃ni Sennakeribu ọba Assiria mu ọ̀na rẹ̀ pọ̀n, o si lọ, o si pada, o si joko ni Ninefe.

37. O si ṣe, bi o ti mbọ̀riṣa ni ile Nisroku oriṣa rẹ̀, ni Adrammeleki ati Ṣareseri awọn ọmọ rẹ̀ fi idà pa a: nwọn si sa lọ si ilẹ Armenia. Esarhaddoni ọmọ rẹ̀ sì jọba ni ipò rẹ̀.