Yorùbá Bibeli

2. A. Ọba 19:31-37 Yorùbá Bibeli (YCE)

31. Nitori lati Jerusalemu li awọn iyokù yio jade lọ, ati awọn ti o salà lati oke Sioni jade: itara Oluwa awọn ọmọ-ogun ni yio ṣe eyi.

32. Nitori bayi li Oluwa wi niti ọba Assiria, On kì yio wá si ilu yi, bẹ̃ni kì yio ta ọfà kan sibẹ, kì yio mu asà wá iwaju rẹ̀, bẹ̃ni kì yio mọ odi tì i yika.

33. Ọna na ti o ba wá, ọkanna ni yio ba pada lọ, kì yio si wá si ilu yi, li Oluwa wi.

34. Nitori emi o da abò bò ilu yi, lati gbà a, nitori ti emi tikara mi, ati nitori ti Dafidi iranṣẹ mi.

35. O si ṣe li oru na ni angeli Oluwa jade lọ, o si pa ọkẹ́ mẹsan le ẹgbẹ̃dọgbọn enia ni ibùbo awọn ara Assiria: nigbati nwọn si dide ni kutukutu owurọ, kiyesi i, okú ni gbogbo wọn jasi.

36. Bẹ̃ni Sennakeribu ọba Assiria mu ọ̀na rẹ̀ pọ̀n, o si lọ, o si pada, o si joko ni Ninefe.

37. O si ṣe, bi o ti mbọ̀riṣa ni ile Nisroku oriṣa rẹ̀, ni Adrammeleki ati Ṣareseri awọn ọmọ rẹ̀ fi idà pa a: nwọn si sa lọ si ilẹ Armenia. Esarhaddoni ọmọ rẹ̀ sì jọba ni ipò rẹ̀.