Yorùbá Bibeli

2. A. Ọba 17:15-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

15. Nwọn si kọ̀ ilana rẹ̀, ati majẹmu rẹ̀ silẹ, ti o ba awọn baba wọn dá, ati ẹri rẹ̀ ti o jẹ si wọn: nwọn si ntọ̀ ohun asan lẹhin, nwọn si huwa asan, nwọn si ntọ̀ awọn keferi lẹhin ti o yi wọn ka, niti ẹniti Oluwa ti kilọ fun wọn pe, ki nwọn ki o máṣe ṣe bi awọn.

16. Nwọn si kọ̀ gbogbo ofin Oluwa Ọlọrun wọn silẹ, nwọn si ṣe ere didà fun ara wọn, ani, ẹgbọ̀rọ malu meji, nwọn si ṣe ere oriṣa, nwọn si mbọ gbogbo ogun ọrun, nwọn si sìn Baali.

17. Nwọn si mu ki awọn ọmọkunrin wọn ati ọmọbinrin wọn ki o kọja lãrin iná, nwọn si nfọ̀ afọ̀ṣẹ, nwọn si nṣe alupayida, nwọn si tà ara wọn lati ṣe ibi niwaju Oluwa, lati mu u binu.

18. Nitorina ni Oluwa ṣe binu si Israeli gidigidi, o si mu wọn kuro niwaju rẹ̀: ọkan kò kù bikòṣe ẹ̀ya Juda nikanṣoṣo.

19. Juda pẹlu kò pa aṣẹ Oluwa Ọlọrun wọn mọ́, ṣugbọn nwọn rìn ninu ilana Israeli ti nwọn ṣe.

20. Oluwa si kọ̀ gbogbo iru-ọmọ Israeli silẹ, o si wahala wọn, o si fi wọn le awọn akoni lọwọ, titi o si fi ta wọn nù kuro niwaju rẹ̀.

21. Nitori ti o yà Israeli kuro ni idile Dafidi; nwọn si fi Jeroboamu ọmọ Nebati jọba: Jeroboamu si tì Israeli kuro lati má tọ̀ Oluwa lẹhin, o si mu wọn ṣẹ̀ ẹ̀ṣẹ nla.

22. Nitoriti awọn ọmọ Israeli rìn ninu gbogbo ẹ̀ṣẹ Jeroboamu ti o ṣẹ̀; nwọn kò lọ kuro ninu wọn;

23. Titi Oluwa fi mu Israeli kuro niwaju rẹ̀, bi o ti sọ nipa gbogbo awọn woli iranṣẹ rẹ̀. Bẹ̃li a kó Israeli kuro ni ilẹ wọn lọ si Assiria, titi di oni yi.