Yorùbá Bibeli

2. A. Ọba 17:1-3 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. LI ọdun kejila Ahasi ọba Juda ni Hoṣea ọmọ Ela bẹ̀rẹ si ijọba ni Samaria, lori Israeli li ọdun mẹsan.

2. O si ṣe eyiti o buru li oju Oluwa, ṣugbọn kì iṣe bi awọn ọba Israeli ti o ti wà ṣãju rẹ̀.

3. On ni Ṣalamaneseri ọba Assiria gòke tọ̀ wá; Hoṣea si di iranṣẹ rẹ̀, o si ta a li ọrẹ.