Yorùbá Bibeli

2. A. Ọba 14:7-16 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. On pa ẹgbãrun ninu awọn ara Edomu ni afonifojì iyọ, o si fi ogun kó Sela, o si pè orukọ rẹ̀ ni Jokteeli titi di oni yi.

8. Nigbana ni Amasiah rán ikọ̀ si Jehoaṣi, ọmọ Jehoahasi ọmọ Jehu, ọba Israeli wipe, Wá, jẹ ki a wò ara wa li oju.

9. Jehoaṣi ọba Israeli si ranṣẹ si Amasiah ọba Juda, pe, Igi ẹgún ti mbẹ ni Lebanoni ranṣẹ si igi kedari ti mbẹ ni Lebanoni pe, Fi ọmọbinrin rẹ fun ọmọ ọkunrin mi li aya: ẹranko igbẹ́ kan ti mbẹ ni Lebanoni kọja lọ, o si tẹ̀ igi ẹ̀gun na mọlẹ.

10. Iwọ ti ṣẹgun Edomu nitõtọ, ọkàn rẹ si gbé ọ soke: mã ṣogo, ki o si gbe ile rẹ: nitori kini iwọ ṣe nfiràn si ifarapa rẹ, ki iwọ ki o lè ṣubu, iwọ, ati Juda pẹlu rẹ?

11. Ṣugbọn Amasiah kò fẹ igbọ́. Nitorina Jehoaṣi ọba Israeli gòke lọ; on ati Amasiah ọba Juda si wò ara wọn li oju ni Betṣemeṣi, ti iṣe ti Juda.

12. A si le Juda niwaju Israeli; nwọn si sá olukuluku sinu agọ rẹ̀.

13. Jehoaṣi ọba Israeli si mu Amasiah ọba Juda, ọmọ Jehoaṣi ọmọ Ahasiah ni Betṣemeṣi, o si wá si Jerusalemu, o si wó odi Jerusalemu palẹ lati ẹnu bodè Efraimu titi de ẹnu bodè igun, irinwo igbọnwọ.

14. O si kó gbogbo wura ati fadakà, ati gbogbo ohun èlo ti a ri ninu ile Oluwa, ati ninu iṣura ile ọba, ati ògo, o si pada si Samaria.

15. Ati iyokù iṣe Jehoaṣi ti o ṣe, ati agbara rẹ̀, ati bi o ti ba Amasiah ọba Judah jà, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli?

16. Jehoaṣi si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, a si sin i ni Samaria pẹlu awọn ọba Israeli; Jeroboamu ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.