Yorùbá Bibeli

2. A. Ọba 14:28-29 Yorùbá Bibeli (YCE)

28. Ati iyokù iṣe Jeroboamu ati gbogbo eyiti o ṣe, ati agbara rẹ̀, bi o ti jagun si, ati bi o ti gbà Damasku, ati Hamati, ti iṣe ti Juda, pada fun Israeli, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli?

29. Jeroboamu si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, ani, pẹlu awọn ọba Israeli; Sakariah ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.