Yorùbá Bibeli

2. A. Ọba 14:1-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. LI ọdun keji Joaṣi ọmọ Jehoahasi ọba Israeli ni Amasiah ọmọ Joaṣi jọba lori Juda.

2. Ẹni ọdun mẹ̃dọgbọ̀n li on iṣe nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba ọdun mọkandilọgbọ̀n ni Jerusalemu. Orukọ iya rẹ̀ a si ma jẹ Jehoadani ti Jerusalemu.

3. On si ṣe eyiti o tọ́ li oju Oluwa, ṣugbọn kì iṣe bi Dafidi baba rẹ̀: o ṣe gẹgẹ bi ohun gbogbo ti Joaṣi baba rẹ̀ ti ṣe.

4. Kiki a kò mu ibi giga wọnni kuro; sibẹ awọn enia nṣe irubọ, nwọn si nsun turari ni ibi giga wọnni.

5. O si ṣe bi ijọba na ti fi idi mulẹ lọwọ rẹ̀ ni o pa awọn iranṣẹ rẹ̀ ti o ti pa ọba baba rẹ̀.

6. Ṣugbọn awọn ọmọ awọn apania na ni kò pa: gẹgẹ bi eyiti a ti kọ ninu iwe ofin Mose ninu eyiti Oluwa paṣẹ wipe, A kò gbọdọ pa baba fun ọmọ, bẹ̃ni a kò gbọdọ pa ọmọ fun baba; ṣugbọn olukuluku li a o pa fun ẹ̀ṣẹ rẹ̀.

7. On pa ẹgbãrun ninu awọn ara Edomu ni afonifojì iyọ, o si fi ogun kó Sela, o si pè orukọ rẹ̀ ni Jokteeli titi di oni yi.

8. Nigbana ni Amasiah rán ikọ̀ si Jehoaṣi, ọmọ Jehoahasi ọmọ Jehu, ọba Israeli wipe, Wá, jẹ ki a wò ara wa li oju.

9. Jehoaṣi ọba Israeli si ranṣẹ si Amasiah ọba Juda, pe, Igi ẹgún ti mbẹ ni Lebanoni ranṣẹ si igi kedari ti mbẹ ni Lebanoni pe, Fi ọmọbinrin rẹ fun ọmọ ọkunrin mi li aya: ẹranko igbẹ́ kan ti mbẹ ni Lebanoni kọja lọ, o si tẹ̀ igi ẹ̀gun na mọlẹ.

10. Iwọ ti ṣẹgun Edomu nitõtọ, ọkàn rẹ si gbé ọ soke: mã ṣogo, ki o si gbe ile rẹ: nitori kini iwọ ṣe nfiràn si ifarapa rẹ, ki iwọ ki o lè ṣubu, iwọ, ati Juda pẹlu rẹ?

11. Ṣugbọn Amasiah kò fẹ igbọ́. Nitorina Jehoaṣi ọba Israeli gòke lọ; on ati Amasiah ọba Juda si wò ara wọn li oju ni Betṣemeṣi, ti iṣe ti Juda.