Yorùbá Bibeli

2. A. Ọba 12:19-21 Yorùbá Bibeli (YCE)

19. Ati iyokù iṣe Joaṣi, ati ohun gbogbo ti o ṣe, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Juda?

20. Awọn iranṣẹ rẹ̀ si dide, nwọn si dì rikiṣi, nwọn si pa Joaṣi ni ile Millo, ti o sọ̀kalẹ lọ si Silla.

21. Nitori Josakari ọmọ Simeati ati Jehosabadi ọmọ Ṣomeri, awọn iranṣẹ rẹ̀ pa a, o si kú; nwọn si sìn i pẹlu awọn baba rẹ̀ ni ilu Dafidi: Amasiah ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.