Yorùbá Bibeli

2. A. Ọba 12:18-21 Yorùbá Bibeli (YCE)

18. Jehoaṣi ọba Juda si mu gbogbo ohun èlo mimọ́ ti Jehoṣafati, ati Jehoramu, ati Ahasiah awọn baba rẹ̀, awọn ọba Juda ti yà si mimọ́, ati ohun mimọ́ tirẹ̀, ati gbogbo wura ti a ri nibi iṣura ile Oluwa, ati ni ile ọba, o si rán a si Hasaeli ọba Siria: on si lọ kuro ni Jerusalemu.

19. Ati iyokù iṣe Joaṣi, ati ohun gbogbo ti o ṣe, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Juda?

20. Awọn iranṣẹ rẹ̀ si dide, nwọn si dì rikiṣi, nwọn si pa Joaṣi ni ile Millo, ti o sọ̀kalẹ lọ si Silla.

21. Nitori Josakari ọmọ Simeati ati Jehosabadi ọmọ Ṣomeri, awọn iranṣẹ rẹ̀ pa a, o si kú; nwọn si sìn i pẹlu awọn baba rẹ̀ ni ilu Dafidi: Amasiah ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.