Yorùbá Bibeli

2. A. Ọba 10:16-21 Yorùbá Bibeli (YCE)

16. On si wipe, Ba mi lọ ki o si wò itara mi fun Oluwa. Bẹ̃ni nwọn mu u gùn kẹkẹ́ rẹ̀.

17. Nigbati o si de Samaria, o pa gbogbo awọn ti o kù fun Ahabu ni Samaria, titi o fi run u, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa ti o sọ fun Elijah.

18. Jehu si kó gbogbo awọn enia jọ, o si wi fun wọn pe, Ahabu sìn Baali diẹ, ṣugbọn Jehu yio sìn i pupọ.

19. Njẹ nitorina, ẹ pè gbogbo awọn woli Baali fun mi, gbogbo awọn iranṣẹ rẹ̀, ati gbogbo awọn alufa rẹ̀; máṣe jẹ ki ọkan ki o kù; nitoriti mo ni ẹbọ nla iṣe si Baali: ẹnikẹni ti o ba kù, kì yio yè. Ṣugbọn Jehu fi ẹ̀tan ṣe e, nitori ki o le pa awọn olùsin Baali run.

20. Jehu si wipe, Ẹ yà apejọ si mimọ́ fun Baali; nwọn si kede rẹ̀.

21. Jehu si ranṣẹ si gbogbo Israeli; gbogbo awọn olùsin Baali si wá tobẹ̃ ti kò si kù ọkunrin kan ti kò wá. Nwọn si wá sinu ile Baali; ile Baali si kún lati ikangun ekini titi de ekeji.