Yorùbá Bibeli

2. A. Ọba 10:1-6 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. AHABU si ni ãdọrin ọmọ ọkunrin ni Samaria. Jehu si kọwe, o si ranṣẹ si Samaria si awọn olori Jesreeli, si awọn àgbagba, ati si awọn ti ntọ́ awọn ọmọ Ahabu, wipe,

2. Njẹ nisisiyi nigbati iwe yi ba ti de ọdọ nyin, bi o ti jẹpe, awọn ọmọ oluwa nyin mbẹ lọdọ nyin, ati kẹkẹ́ ati ẹṣin mbẹ lọdọ nyin, ilu olodi pẹlu ati ihamọra.

3. Ki ẹ wò ẹniti o sàn jùlọ ati ti o si yẹ jùlọ ninu awọn ọmọ oluwa nyin, ki ẹ gbé e ka ori-itẹ́ baba rẹ̀, ki ẹ si jà fun ile oluwa nyin.

4. Ṣugbọn ẹ̀ru bà wọn gidigidi, nwọn si wipe, Kiyesi i, ọba meji kò duro niwaju rẹ̀: awa o ha ti ṣe le duro?

5. Ati ẹniti iṣe olori ile, ati ẹniti iṣe olori ilu, awọn àgbagba pẹlu, ati awọn olutọ́ awọn ọmọ, ranṣẹ si Jehu wipe, Iranṣẹ rẹ li awa, a o si ṣe gbogbo ohun ti o ba pa li aṣẹ fun wa; awa kì yio jẹ ọba: iwọ ṣe eyi ti o dara li oju rẹ.

6. Nigbana ni o kọ iwe lẹrinkeji si wọn wipe, Bi ẹnyin ba ṣe ti emi, bi ẹnyin o si fi eti si ohùn mi, ẹ mu ori awọn ọkunrin na, awọn ọmọ oluwa nyin, ki ẹ si tọ̀ mi wá ni Jesreeli ni iwòyi ọla. Njẹ awọn ọmọ ọba, ãdọrin ọkunrin, mbẹ pẹlu awọn enia nla ilu na ti ntọ́ wọn.