Yorùbá Bibeli

Ifi 1:2-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

2. Ẹniti o jẹri ọ̀rọ Ọlọrun, ati ẹrí Jesu Kristi, ati ti ohun gbogbo ti o ri.

3. Olubukún li ẹniti nkà, ati awọn ti o ngbọ́ ọ̀rọ isọtẹlẹ yi, ti o si npa nkan wọnni ti a kọ sinu rẹ̀ mọ́: nitori igba kù si dẹ̀dẹ.

4. JOHANU si ìjọ meje ti mbẹ ni Asia: Ore-ọfẹ fun nyin, ati alafia, lati ọdọ ẹniti o mbẹ, ti o si ti wà, ti o si mbọ̀wá; ati lati ọdọ awọn Ẹmí meje ti mbẹ niwaju itẹ́ rẹ̀;

5. Ati lati ọdọ Jesu Kristi, ẹlẹri olõtọ, akọbi ninu awọn okú, ati alaṣẹ awọn ọba aiye. Ẹniti o fẹ wa, ti o si wẹ̀ wa ninu ẹ̀jẹ rẹ̀ kuro ninu ẹ̀ṣẹ wa,

6. Ti o si ti fi wa jẹ́ ọba ati alufa fun Ọlọrun ati Baba rẹ̀; tirẹ̀ li ogo ati ijọba lai ati lailai. Amin.

7. Kiyesi i, o mbọ̀ ninu awọsanma; gbogbo oju ni yio si ri i, ati awọn ti o gún u li ọ̀kọ pẹlu; ati gbogbo orilẹ-ede aiye ni yio si mã pohùnrere ẹkún niwaju rẹ̀. Bẹ̃na ni. Amin.

8. Emi ni Alfa ati Omega, ipilẹṣẹ ati opin, li Oluwa wi, ẹniti o mbẹ, ti o ti wà, ti o si mbọ̀wá, Olodumare.

9. Emi Johanu, arakunrin nyin ati alabapin pẹlu nyin ninu wahala ati ijọba ati sũru ti mbẹ ninu Jesu, wà ninu erekuṣu ti a npè ni Patmo, nitori ọ̀rọ Ọlọrun, ati nitori ẹrí Jesu Kristi.

10. Mo wà ninu Ẹmí li ọjọ Oluwa, mo si gbọ́ ohùn nla kan lẹhin mi, bi iró ipè,