Yorùbá Bibeli

1. A. Ọba 22:43-53 Yorùbá Bibeli (YCE)

43. O si rin ni gbogbo ọ̀na Asa baba rẹ̀; kò yipada kuro ninu rẹ̀, o nṣe eyiti o tọ li oju Oluwa: kiki a kò mu awọn ibi giga kuro; awọn enia si nrú ẹbọ, nwọn si nsun turari sibẹ̀ ni ibi giga wọnni.

44. Jehoṣafati si wà li alafia pẹlu ọba Israeli.

45. Ati iyokù iṣe Jehoṣafati ati iṣe agbara rẹ̀ ti o ṣe, ati bi o ti jagun si, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Juda?

46. Iyokù awọn ti nhuwà panṣaga ti o kù li ọjọ Asa baba rẹ̀, li o parun kuro ni ilẹ na.

47. Nigbana kò si ọba ni Edomu: adelé kan li ọba.

48. Jehoṣafati kàn ọkọ̀ Tarṣiṣi lati lọ si Ofiri fun wura; ṣugbọn nwọn kò lọ: nitori awọn ọkọ̀ na fọ́ ni Esion-Geberi.

49. Nigbana ni Ahasiah, ọmọ Ahabu, wi fun Jehoṣafati pe, Jẹ ki awọn iranṣẹ mi ba awọn iranṣẹ rẹ lọ ninu ọkọ̀. Ṣugbọn Jehoṣafati kọ̀.

50. Jehoṣafati si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, a si sin i pẹlu awọn baba rẹ̀ ni ilu Dafidi, baba rẹ̀: Jehoramu, ọmọ rẹ̀, si jọba ni ipò rẹ̀.

51. Ahasiah, ọmọ Ahabu, bẹ̀rẹ si ijọba lori Israeli ni Samaria li ọdun kẹtadilogun Jehoṣafati, ọba Juda, o si jọba li ọdun meji lori Israeli.

52. O si ṣe ibi niwaju Oluwa, o si rìn li ọ̀na baba rẹ̀, ati li ọ̀na iya rẹ̀, ati li ọ̀na Jeroboamu, ọmọ Nebati, ti o mu Israeli dẹ̀ṣẹ:

53. Nitoriti o sin Baali, o si mbọ ọ, o si mu Oluwa, Ọlọrun Israeli binu, gẹgẹ bi gbogbo eyiti baba rẹ̀ ti ṣe.