Yorùbá Bibeli

1. A. Ọba 22:35-46 Yorùbá Bibeli (YCE)

35. Ogun na si le li ọjọ na: a si dá ọba duro ninu kẹkẹ́ kọju si awọn ara Siria, o si kú li aṣalẹ, ẹ̀jẹ si ṣàn jade lati inu ọgbẹ na si ãrin kẹkẹ́ na.

36. A si kede la ibudo já li akokò iwọ̀ õrun wipe, Olukuluku si ilu rẹ̀, ati olukuluku si ilẹ rẹ̀.

37. Bẹ̃ni ọba kú, a si gbe e wá si Samaria; nwọn si sin ọba ni Samaria.

38. Ẹnikan si wẹ kẹkẹ́ na ni adagun Samaria, awọn ajá si la ẹ̀jẹ rẹ̀; awọn àgbere si wẹ ara wọn ninu rẹ̀ gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa ti o sọ,

39. Ati iyokù iṣe Ahabu, ati gbogbo eyi ti o ṣe, ati ile ehin-erin ti o kọ́, ati gbogbo ilu ti o tẹ̀do, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli?

40. Ahabu si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀; Ahasiah, ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.

41. Jehoṣafati, ọmọ Asa, si bẹ̀rẹ si ijọba lori Juda li ọdun kẹrin Ahabu, ọba Israeli.

42. Jehoṣafati si to ẹni ọdun marundilogoji nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba; o si jọba ọdun mẹ̃dọgbọn ni Jerusalẹmu. Orukọ iya rẹ̀ ni Asuba ọmọbinrin Ṣilhi.

43. O si rin ni gbogbo ọ̀na Asa baba rẹ̀; kò yipada kuro ninu rẹ̀, o nṣe eyiti o tọ li oju Oluwa: kiki a kò mu awọn ibi giga kuro; awọn enia si nrú ẹbọ, nwọn si nsun turari sibẹ̀ ni ibi giga wọnni.

44. Jehoṣafati si wà li alafia pẹlu ọba Israeli.

45. Ati iyokù iṣe Jehoṣafati ati iṣe agbara rẹ̀ ti o ṣe, ati bi o ti jagun si, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Juda?

46. Iyokù awọn ti nhuwà panṣaga ti o kù li ọjọ Asa baba rẹ̀, li o parun kuro ni ilẹ na.