Yorùbá Bibeli

1. A. Ọba 21:1-9 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. O si ṣe lẹhin nkan wọnyi, Naboti, ara Jesreeli, ni ọgba-ajara ti o wà ni Jesreeli, ti o sunmọ ãfin Ahabu, ọba Samaria girigiri.

2. Ahabu si ba Naboti sọ wipe, Fun mi ni ọgba-ajara rẹ, ki emi ki o fi ṣe ọgba-ewebẹ̀, nitori ti o sunmọ ile mi: emi o si fun ọ li ọgba-ajara ti o san jù u lọ dipò rẹ̀; bi o ba si dara li oju rẹ, emi o fi iye-owo rẹ̀ fun ọ.

3. Naboti si wi fun Ahabu pe, Oluwa má jẹ ki emi fi ogún awọn baba mi fun ọ.

4. Ahabu si wá si ile rẹ̀, o wugbọ, inu rẹ̀ si bajẹ nitori ọ̀rọ ti Naboti, ara Jesreeli, sọ fun u: nitoriti on ti wipe, emi kì o fun ọ ni ogún awọn baba mi. On si dubulẹ lori akete rẹ̀, o si yi oju rẹ̀ padà, kò si fẹ ijẹun.

5. Jesebeli, aya rẹ̀ si tọ̀ ọ wá o si wi fun u pe, Ẽṣe ti inu rẹ fi bajẹ́ ti iwọ kò fi jẹun?

6. O si wi fun u pe, Nitoriti mo ba Naboti, ara Jesreeli sọ, mo si wi fun u pe, Fun mi ni ọgba-àjara rẹ fun owo; tabi bi o ba wù ọ, emi o fun ọ ni ọgba-àjara miran ni ipò rẹ̀: o si dahùn wipe, Emi kì o fun ọ ni ọgba-àjara mi.

7. Jesebeli, aya rẹ̀ si wi fun u pe, iwọ kò ha jọba lori Israeli nisisiyi? Dide, jẹun, ki o si jẹ ki inu rẹ ki o dùn! emi o fun ọ ni ọgba-àjara Nãboti ara Jesreeli.

8. Bẹ̃ni o kọwe li orukọ Ahabu, o si fi èdidi rẹ̀ di i, o si fi iwe na ṣọwọ sọdọ awọn àgbagba ati awọn ọlọla ti mbẹ ni ilu rẹ̀, ti o si mba Naboti gbe.

9. O si kọ sinu iwe na pe, Ẹ kede àwẹ, ki ẹ si fi Naboti si ipò ọla lãrin awọn enia.