8. Ati gbogbo awọn àgba ati gbogbo awọn enia wi fun u pe, Máṣe fi eti si tirẹ̀, bẹ̃ni ki o máṣe gbà fun u.
9. Nitorina li o sọ fun awọn onṣẹ Benhadadi pe, Wi fun oluwa mi ọba pe, ohun gbogbo ti iwọ ranṣẹ fun, sọdọ iranṣẹ rẹ latetekọṣe li emi o ṣe: ṣugbọn nkan yi li emi kò le ṣe. Awọn onṣẹ na pada lọ, nwọn si tun mu èsi fun u wá.
10. Benhadadi si ranṣẹ si i, o si wipe, Ki awọn oriṣa ki o ṣe bẹ̃ si mi, ati jù bẹ̃ lọ pẹlu bi ẽkuru Samaria yio to fun ikunwọ fun gbogbo enia ti ntẹle mi.
11. Ọba Israeli si dahùn, o si wipe, Wi fun u pe, Má jẹ ki ẹniti nhamọra, ki o halẹ bi ẹniti mbọ́ ọ silẹ,
12. O si ṣe, nigbati Benhadadi gbọ́ ọ̀rọ yi, bi o ti nmuti, on ati awọn ọba ninu agọ, li o sọ fun awọn iranṣẹ rẹ̀ pe, Ẹ tẹ́gun si ilu na.
13. Si kiyesi i, woli kan tọ̀ Ahabu, ọba Israeli wá, wipe, Bayi li Oluwa wi, Iwọ ri gbogbo ọ̀pọlọpọ yi? kiyesi i, emi o fi wọn le ọ lọwọ loni; iwọ o si mọ̀ pe, Emi li Oluwa.
14. Ahabu wipe, Nipa tani? On si wipe, Bayi li Oluwa wi, Nipa awọn ipẹrẹ̀ awọn ijoye igberiko. Nigbana li o wipe, Tani yio wé ogun na? On si dahùn pe: Iwọ.
15. Nigbana li o kà awọn ipẹrẹ̀ awọn ijoye igberiko, nwọn si jẹ igba o le mejilelọgbọn: lẹhin wọn li o si kà gbogbo awọn enia, ani gbogbo awọn ọmọ Israeli jẹ ẹdẹgbarin.
16. Nwọn si jade lọ li ọjọ-kanri. Ṣugbọn Benhadadi mu amupara ninu agọ, on, ati awọn ọba, awọn ọba mejilelọgbọn ti nràn a lọwọ.
17. Awọn ipẹrẹ̀ awọn ijoye igberiko tètekọ jade lọ: Benhadadi si ranṣẹ jade, nwọn si sọ fun u wipe, awọn ọkunrin nti Samaria jade wá.
18. On si wipe, Bi nwọn ba bá ti alafia jade, ẹ mu wọn lãye; tabi bi ti ogun ni nwọn ba bá jade, ẹ mu wọn lãye.
19. Bẹ̃ni awọn ipẹrẹ̀ wọnyi ti awọn ijoye igberiko jade ti ilu wá, ati ogun ti o tẹle wọn.