Yorùbá Bibeli

1. A. Ọba 20:32-38 Yorùbá Bibeli (YCE)

32. Bẹ̃ni nwọn di aṣọ ọ̀fọ mọ ẹgbẹ wọn, nwọn si fi ijara yi ori wọn ka, nwọn si tọ̀ ọba Israeli wá, nwọn si wipe, Benhadadi, iranṣẹ rẹ, wipe, Emi bẹ ọ, jẹ ki ẹmi mi ki o yè. On si wipe, O mbẹ lãye sibẹ? arakunrin mi li on iṣe.

33. Awọn ọkunrin na si ṣe akiyesi gidigidi, nwọn si yara gbá ohun ti o ti ọdọ rẹ̀ wá mu: nwọn si wipe, Benhadadi arakunrin rẹ! Nigbana li o wipe, Ẹ lọ mu u wá. Nigbana ni Benhadadi jade tọ̀ ọ wá; o si mu u goke wá sinu kẹkẹ́.

34. On si wi fun u pe, Awọn ilu ti baba mi gbà lọwọ baba rẹ, emi o mu wọn pada: iwọ o si là ọ̀na fun ara rẹ ni Damasku, bi baba mi ti ṣe ni Samaria. Nigbana ni Ahabu wipe, Emi o rán ọ lọ pẹlu majẹmu yi. Bẹ̃ li o ba a dá majẹmu, o si rán a lọ.

35. Ọkunrin kan ninu awọn ọmọ awọn woli si wi fun ẹnikeji rẹ̀ nipa ọ̀rọ Oluwa pe, Jọ̃, lù mi. Ọkunrin na si kọ̀ lati lù u.

36. Nigbana li o wi pe, Nitoriti iwọ kò gbà ohùn Oluwa gbọ́, kiyesi i, bi iwọ ba ti ọdọ mi kuro, kiniun yio pa ọ. Bi o si ti jade lọ lọdọ rẹ̀, kiniun kan ri i o si pa a.

37. Nigbana li o si ri ọkunrin miran, o si wipe, Jọ̃, lù mi. Ọkunrin na si lù u, ni lilu ti o lù u, o pa a lara.

38. Woli na si lọ, o si duro de ọba loju ọ̀na, o pa ara rẹ̀ da, ni fifi ẽru ba oju.