Yorùbá Bibeli

1. A. Ọba 12:28-33 Yorùbá Bibeli (YCE)

28. Ọba si gbìmọ, o si ya ẹgbọ̀rọ malu wura meji, o si wi fun wọn pe, O pọ̀ju fun nyin lati mã goke lọ si Jerusalemu: Israeli, wò awọn ọlọrun rẹ, ti o mu ọ lati ilẹ Egipti wá!

29. O si gbe ọkan kalẹ ni Beteli, ati ekeji li o fi si Dani.

30. Nkan yi si di ẹ̀ṣẹ: nitori ti awọn enia lọ lati sìn niwaju ọkan, ani titi de Dani.

31. O si kọ́ ile ibi giga wọnni, o si ṣe alufa lati inu awọn enia, ti kì iṣe inu awọn ọmọ Lefi.

32. Jeroboamu si dá àse silẹ li oṣu kẹjọ, li ọjọ Kẹdogun oṣu, gẹgẹ bi àse ti o wà ni Juda, o si gun ori pẹpẹ na lọ: bẹ̃ni o si ṣe ni Beteli, o rubọ si awọn ọmọ-malu ti o ṣe: o si fi awọn alufa ibi giga wọnni ti o ti ṣe si Beteli.

33. O si gun ori pẹpẹ na lọ ti o ti ṣe ni Beteli li ọjọ kẹdogun oṣu kẹjọ, li oṣu ti o rò li ọkàn ara rẹ̀; o si da àse silẹ fun awọn ọmọ Israeli; o si gun ori pẹpẹ na lọ, lati fi turari jona.