Yorùbá Bibeli

1. A. Ọba 12:1-13 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. REHOBOAMU si lọ si Ṣekemu, nitori gbogbo Israeli li o wá si Ṣekemu lati fi i jẹ ọba.

2. O si ṣe, nigbati Jeroboamu, ọmọ Nebati, ti o wà ni Egipti sibẹ gbọ́, nitori ti o ti sá kuro niwaju Solomoni ọba, Jeroboamu si joko ni Egipti.

3. Nwọn si ranṣẹ pè e, ati Jeroboamu ati gbogbo ijọ Israeli wá, nwọn si sọ fun Rehoboamu wipe,

4. Baba rẹ sọ àjaga wa di wuwo: njẹ nitorina, ṣe ki ìsin baba rẹ ti o le, ati àjaga rẹ̀ ti o wuwo, ti o fi si wa li ọrùn, ki o fẹrẹ̀ diẹ, awa o si sìn ọ.

5. O si wi fun wọn pe, Ẹ lọ na titi di ijọ mẹta, nigbana ni ki ẹ pada tọ̀ mi wá. Awọn enia na si lọ.

6. Rehoboamu ọba si ba awọn àgbagba, ti imã duro niwaju Solomoni, baba rẹ̀, nigbati o wà lãye, gbimọ̀ wipe, Imọran kili ẹnyin dá, ki emi ki o lè da awọn enia yi lohùn?

7. Nwọn si wi fun u pe, Bi iwọ o ba jẹ iranṣẹ fun awọn enia yi loni, ti iwọ o si sin wọn, ti iwọ o si da wọn lohùn, ati ti iwọ o sọ̀rọ rere fun wọn, nwọn o ṣe iranṣẹ rẹ titi lai.

8. Ṣugbọn o kọ̀ ìmọran awọn àgbagba ti nwọn ba a dá, o si ba awọn ipẹrẹ ti nwọn dagba pẹlu rẹ̀, ti nwọn si duro niwaju rẹ̀ gbimọ̀.

9. O si wi fun wọn pe, Imọran kini ẹnyin dá ki awa ki o le dá awọn enia yi lohùn, ti nwọn ba mi sọ wipe, Ṣe ki àjaga ti baba rẹ fi si wa lọrùn ki o fuyẹ diẹ?

10. Awọn ipẹrẹ ti o dagba pẹlu rẹ̀ wi fun u pe, Bayi ni ki iwọ ki o wi fun awọn enia yi ti nwọn ba ọ sọ wipe, Baba rẹ mu ki àjaga wa di wuwo, sugbọn iwọ mu ki o fuyẹ diẹ fun wa; bayi ni ki iwọ ki o sọ fun wọn: ọmọdirin mi yio nipọn jù ẹgbẹ́ baba mi lọ.

11. Njẹ nisisiyi, baba mi ti gbe àjaga wuwo kà nyin, emi o si fi kún àjaga nyin: baba mi ti fi paṣan nà nyin, sugbọn emi o fi akẽke nà nyin.

12. Bẹ̃ni Jeroboamu ati gbogbo awọn enia na wá sọdọ Rehoboamu ni ijọ kẹta, gẹgẹ bi ọba ti dá wipe, Ẹ pada tọ̀ mi wá ni ijọ kẹta.

13. Ọba si da awọn enia li ohùn akọ, o si kọ̀ ìmọran awọn àgbagba ti nwọn ba a dá.