Yorùbá Bibeli

Eks 32:22-35 Yorùbá Bibeli (YCE)

22. Aaroni si wipe, Máṣe jẹ ki ibinu oluwa mi ki o gbona: iwọ mọ̀ awọn enia yi pe, nwọn buru.

23. Awọn li o sa wi fun mi pe, Ṣe oriṣa fun wa, ti yio ma ṣaju wa: bi o ṣe ti Mose yi ni, ọkunrin nì ti o mú wa gòke lati ilẹ Egipti wá, awa kò mọ̀ ohun ti o ṣe e.

24. Emi si wi fun wọn pe, Ẹnikẹni ti o ba ni wurà, ki nwọn ki o kán a kuro; bẹ̃ni nwọn fi fun mi: nigbana li emi fi i sinu iná, ẹgbọrọmalu yi si ti jade wá.

25. Nigbati Mose ri i pe awọn enia na kò ṣe ikoso; nitoriti Aaroni sọ wọn di alailakoso lãrin awọn ti o dide si wọn.

26. Nigbana ni Mose duro li ẹnubode ibudó, o si wipe, Ẹnikẹni ti o wà ni ìha ti OLUWA, ki o tọ̀ mi wá. Gbogbo awọn ọmọ Lefi si kó ara wọn jọ sọdọ rẹ̀.

27. O si wi fun wọn pe, Bayi li OLUWA, Ọlọrun Israeli, wipe, Ki olukuluku ọkunrin ki o kọ idà rẹ̀ si ẹgbẹ́ rẹ̀, ki ẹ si ma wọle, ki ẹ si ma jade lati ẹnubode dé ẹnubode já gbogbo ibudó, olukuluku ki o si pa arakunrin rẹ̀, ati olukuluku ki o si pa ẹgbẹ rẹ̀, ati olukuluku ki o si pa aladugbo rẹ̀.

28. Awọn ọmọ Lefi si ṣe gẹgẹ bi ọ̀rọ Mose: awọn ti o ṣubu ninu awọn enia li ọjọ́ na to ìwọn ẹgbẹdogun enia.

29. Mose sa ti wipe, Ẹ yà ara nyin simimọ́ li oni fun OLUWA, ani olukuluku ọkunrin lara ọmọ rẹ̀, ati lara arakunrin rẹ̀; ki o le fi ibukún si nyin lori li oni.

30. O si ṣe ni ijọ́ keji, ni Mose wi fun awọn enia pe, Ẹnyin dá ẹ̀ṣẹ nla: njẹ nisisiyi, emi o gòke tọ̀ OLUWA, bọya emi o ṣètutu fun ẹ̀ṣẹ nyin.

31. Mose si pada tọ̀ OLUWA lọ, o si wipe, Yẽ, awọn enia wọnyi ti dá ẹ̀ṣẹ nla, nwọn si dá oriṣa wurà fun ara wọn.

32. Nisisiyi, bi iwọ o ba dari ẹ̀ṣẹ wọn jì wọn; bi bẹ̃ si kọ, emi bẹ̀ ọ, pa mi rẹ́ kuro ninu iwé rẹ ti iwọ ti kọ.

33. OLUWA si wi fun Mose pe, Ẹnikẹni ti o ṣẹ̀ mi, on li emi o parẹ́ kuro ninu iwé mi.

34. Njẹ nisisiyi lọ, ma mú awọn enia na lọ si ibiti mo ti sọ fun ọ: kiyesi i, angeli mi yio ṣaju rẹ: ṣugbọn li ọjọ́ ti emi o ṣe ìbẹwo, emi o bẹ̀ ẹ̀ṣẹ wọn wò lara wọn.

35. OLUWA si yọ awọn enia na lẹnu, nitoriti nwọn ṣe ẹgbọrọ-malu, ti Aaroni ṣe.