Yorùbá Bibeli

Eks 30:21-31 Yorùbá Bibeli (YCE)

21. Nwọn o si wẹ̀ ọwọ́ wọn ati ẹsẹ̀ wọn, ki nwọn ki o má ba kú: yio si di ìlana fun wọn lailai, fun u ati fun irú-ọmọ rẹ̀ lati irandiran wọn.

22. OLUWA si sọ fun Mose pe,

23. Iwọ mú ãyo olõrùn si ọdọ rẹ, pẹlu ojia sísan ẹdẹgbẹta ṣekeli, ati kinnamoni didùn idameji bẹ̃, ani ãdọtalerugba ṣekeli, ati kalamu didùn ãdọtalerugba ṣekeli,

24. Ati kassia ẹdẹgbẹta ṣekeli, ṣekeli ibi mimọ́, ati hini oróro olifi kan:

25. Iwọ o si ṣe e li oróro mimọ́ ikunra, ti a fi ọgbọ́n alapòlu pò: yio si jẹ́ oróro mimọ́ itasori.

26. Iwọ o si ta ninu rẹ̀ sara agọ́ ajọ, ati apoti ẹrí nì,

27. Ati tabili ati ohunèlo rẹ̀ gbogbo, ati ọpáfitila ati ohun-èlo rẹ̀, ati pẹpẹ turari,

28. Ati pẹpẹ ẹbọ sisun pẹlu gbogbo ohunèlo rẹ̀, ati agbada ati ẹsẹ̀ rẹ̀.

29. Iwọ o si yà wọn simimọ́, ki nwọn ki o le ṣe mimọ́ julọ: ohunkohun ti o ba fọwọkàn wọn yio di mimọ́.

30. Iwọ o si ta òróró sí Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀, iwọ o si yà wọn si mimọ́, ki nwọn ki o le ma ṣe alufa fun mi.

31. Iwọ o si sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, Eyi ni yio ma ṣe oróro mimọ́ itasori fun mi lati irandiran nyin.