Yorùbá Bibeli

Eks 28:26-35 Yorùbá Bibeli (YCE)

26. Iwọ o si ṣe oruka wurà meji, iwọ o si fi wọn si eti mejeji igbàiya na li eti rẹ̀, ti o wà ni ìha ẹ̀wu-efodi na ni ìha inú.

27. Iwọ o si ṣe oruka wurà meji, iwọ o si fi wọn si ejika ẹ̀wu-efodi mejeji nisalẹ, si ìha iwaju rẹ̀, ti o kọjusi isolù rẹ̀, loke onirũru-ọnà ọjá ẹ̀wu-efodi na.

28. Nwọn o si fi oruka rẹ̀ so igbàiya na mọ́ oruka ẹ̀wu-efodi na ti on ti ọjá àwọn alaró, ki o le wà loke onirũru-ọnà ọjá ẹ̀wu-efodi na, ki a má si ṣe tú igbàiya na kuro lara ẹ̀wu-efodi na.

29. Aaroni yio si ma rù orukọ awọn ọmọ Israeli ninu igbàiya idajọ li àiya rẹ̀, nigbati o ba nwọ̀ ibi mimọ́ nì lọ, fun iranti nigbagbogbo niwaju OLUWA.

30. Iwọ o si fi Urimu on Tummimu sinu igbàiya idajọ; nwọn o si wà li àiya Aaroni, nigbati o ba nwọle lọ niwaju OLUWA; Aaroni yio si ma rù idajọ awọn ọmọ Israeli li àiya rẹ̀ nigbagbogbo niwaju OLUWA.

31. Iwọ o si ṣe aṣọ igunwa ẹ̀wu-efodi na ni kìki aṣọ-alaró.

32. Oju ọrùn yio si wà lãrin rẹ̀ fun ori; ọjá iṣẹti yio si wà yi oju rẹ̀ ká, iṣẹ-oniṣọnà gẹgẹ bi ẹ̀wu ogun, ki o má ba fàya.

33. Ati ni iṣẹti rẹ̀ nisalẹ ni iwọ o ṣe pomegranate aṣọ-alaró, ati elesè-àluko, ati ododó, yi iṣẹti rẹ̀ ká; ati ṣaworo wurà lãrin wọn yiká;

34. Ṣaworo wurà kan ati pomegranate kan, ṣaworo wurà kan ati pomegranate kan, li eti iṣẹti aṣọ igunwa na yiká.

35. On o si wà lara Aaroni lati ma fi ṣiṣẹ: a o si ma gbọ́ iró rẹ̀ nigbati o ba wọ̀ ibi mimọ́ lọ niwaju OLUWA, ati nigbati o ba si njade bọ̀, ki o má ba kú.