Yorùbá Bibeli

Eks 26:22-37 Yorùbá Bibeli (YCE)

22. Ati fun ìha agọ́ na ni ìha ìwọ-õrùn apáko mẹfa ni ki iwọ ki o ṣe.

23. Ati apáko meji ni iwọ o ṣe fun igun agọ́ na ni ìha ẹhin rẹ̀.

24. A o si so wọn pọ̀ nisalẹ, a o si so wọn pọ̀ li oke ori rẹ̀ si oruka kan: bẹ̃ni yio si ṣe ti awọn mejeji; nwọn o si ṣe ti igun mejeji.

25. Nwọn o si jẹ́ apáko mẹjọ, ati ihò-ìtẹbọ fadakà wọn, ihò-ìtẹbọ mẹrindilogun; ihò-ìtẹbọ meji nisalẹ apáko kan, ati ihò-ìtẹbọ meji nisalẹ apáko keji.

26. Iwọ o si ṣe ọpá idabu igi ṣittimu; marun fun apáko ìha kan agọ́ na,

27. Ati ọpá idabu marun fun apáko na ni ìha keji agọ́ na, ati ọpá idabu marun fun apáko na ni ìha agọ́ na, fun ìha mejeji ni ìha ìwọ-õrùn.

28. Ati ọpá ãrin li agbedemeji apáko wọnni yio ti ìku dé ìku.

29. Iwọ o si fi wurà bò apáko wọnni, iwọ o si fi wurà ṣe oruka wọn li àye fun ọpá idabu wọnni: iwọ o si fi wurà bò ọpá idabu wọnni.

30. Iwọ o si gbé agọ́ na ró, gẹgẹ bi apẹrẹ rẹ̀, ti a fihàn ọ lori oke.

31. Iwọ o si ṣe aṣọ-ikele alaró, ati elesè-àluko, ati ododó, ati ọ̀gbọ olokùn wiwẹ ti iṣẹ ọlọnà: ti on ti awọn kerubu nì ki a ṣe e:

32. Iwọ o si fi rọ̀ sara opó igi ṣittimu mẹrin, ti a fi wurà bò, wurà ni ikọ́ wọn lori ihò-ìtẹbọ fadakà mẹrẹrin na.

33. Iwọ o si ta aṣọ-ikele na si abẹ ikọ́ wọnni, ki iwọ ki o le mú apoti ẹrí nì wá si inu aṣọ-ikele nì: aṣọ-ikele nì ni yio si pinya lãrin ibi mimọ́ ati ibi mimọ́ julọ fun nyin.

34. Iwọ o si fi itẹ́-ãnu sori apoti ẹrí nì, ni ibi mimọ́ julọ.

35. Iwọ o si gbé tabili na kà ẹhin ode aṣọ-ikele nì, ati ọpá-fitila nì kọjusi tabili na ni ìha agọ́ na ni ìha gusù: iwọ o si gbé tabili na kà ìha ariwa.

36. Iwọ o si ṣe aṣọ-tita kan fun ẹnu-ọ̀na agọ́ na, ti aṣọ-alaró, ti elesè-aluko, ti ododó, ati ti ọ̀gbọ olokùn wiwẹ, ti a fi iṣẹ abẹ́rẹ ṣe.

37. Iwọ o si ṣe opó igi ṣittimu marun fun aṣọ-tita na, ki o si fi wurà bò wọn; ati ikọ́ wọn wurà: iwọ o si dà ihò-ìtẹbọ idẹ marun fun wọn.