Yorùbá Bibeli

Eks 25:10-25 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Nwọn o si ṣe apoti igi ṣittimu: igbọnwọ meji on àbọ ni gigùn rẹ̀, ati igbọnwọ kan on àbọ ni ibú rẹ̀, ati igbọnwọ kan on àbọ ni giga rẹ̀.

11. Iwọ o si fi kìki wurà bò o, ninu ati lode ni iwọ o fi bò o, iwọ o si ṣe igbáti wurà sori rẹ̀ yiká.

12. Iwọ o si ṣe oruka wurà mẹrin si i, iwọ o si fi wọn si igun mẹrin rẹ̀; oruka meji yio si wà li apa kini rẹ̀, oruka meji yio si wà li apa keji rẹ̀.

13. Iwọ o si ṣe ọpá ṣittimu, ki iwọ ki o si fi wurà bò wọn.

14. Iwọ o si fi ọpá wọnni bọ̀ inu oruka wọnni ni ìha apoti na, ki a le ma fi wọn gbé apoti na.

15. Ọpá wọnni yio si ma wà ninu oruka apoti na: a ki yio si yọ wọn kuro ninu rẹ̀.

16. Iwọ o si fi ẹrí ti emi o fi fun ọ sinu apoti nì.

17. Iwọ o si fi kìki wurà ṣe itẹ-anu: igbọnwọ meji on àbọ ni gigùn rẹ̀, ati igbọnwọ kan on àbọ ni ibú rẹ̀.

18. Iwọ o si ṣe kerubu wurà meji; ni iṣẹ lilù ni ki iwọ ki o fi ṣe wọn, ni ìku itẹ́-ãnu na mejeji.

19. Si ṣe kerubu kini ni ìku kan, ati kerubu keji ni ìku keji: lati itẹ́-ãnu ni ki ẹnyin ki o ṣe awọn kerubu na ni ìku rẹ̀ mejeji.

20. Awọn kerubu na yio si nà iyẹ́-apa wọn si oke, ki nwọn ki o fi iyẹ́-apa wọn bò itẹ́-ãnu na, ki nwọn ki o si kọjusi ara wọn; itẹ́-ãnu na ni ki awọn kerubu na ki o kọjusi.

21. Iwọ o si fi itẹ́-ãnu na sori apoti na; ati ninu apoti na ni iwọ o fi ẹri ti emi o fi fun ọ si.

22. Nibẹ̀ li emi o ma pade rẹ, emi o si ma bá ọ sọ̀rọ lati oke itẹ́-ãnu wá, lati ãrin awọn kerubu mejeji wá, ti o wà lori apoti ẹrí na, niti ohun gbogbo ti emi o palaṣẹ fun ọ si awọn ọmọ Israeli.

23. Iwọ o si ṣe tabili igi ṣittimu kan: igbọnwọ meji ni gigùn rẹ̀, ati igbọnwọ kan ni ibú rẹ̀, ati igbọnwọ kan on àbọ ni giga rẹ̀.

24. Iwọ o si fi kìki wurà bò o, iwọ o si ṣe igbáti wurà si i yiká.

25. Iwọ o si ṣe eti kan bi ibú-atẹlẹwọ si i yiká, iwọ o si ṣe igbáti wurà si eti rẹ̀ yiká.