20. Nigbati awọn ọkunrin Ai boju wo ẹhin wọn, kiyesi i, nwọn ri ẹ̃fi ilu na ngòke lọ si ọrun, nwọn kò si lí agbara lati gbà ihin tabi ọhún sálọ: awọn enia ti o sá lọ si aginjù si yipada si awọn ti nlepa.
21. Nigbati Joṣua ati gbogbo Israeli ri bi awọn ti o ba ti gbà ilu, ti ẹ̃fi ilu na si gòke, nwọn si yipada, nwọn si pa awọn ọkunrin Ai.
22. Awọn ti ara keji si yọ si wọn lati ilu na wá; bẹ̃ni nwọn wà li agbedemeji Israeli, awọn miran li apa ihin, awọn miran li apa ọhún: nwọn si pa wọn, bẹ̃ni nwọn kò si jẹ ki ọkan ki o kù tabi ki o sálọ ninu wọn.
23. Nwọn si mú ọba Ai lãye, nwọn si mú u wá sọdọ Joṣua.
24. O si ṣe, nigbati Israeli pari pipa gbogbo awọn ara ilu Ai ni igbẹ́, ati ni aginjù ni ibi ti nwọn lé wọn si, ti gbogbo wọn si ti oju idà ṣubu, titi a fi run wọn, ni gbogbo awọn ọmọ Israeli pada si Ai, nwọn si fi oju idà kọlù u.
25. O si ṣe, gbogbo awọn ti o ṣubu ni ijọ́ na, ati ọkunrin ati obinrin, jẹ́ ẹgba mẹfa, ani gbogbo ọkunrin Ai.
26. Nitoriti Joṣua kò fà ọwọ́ rẹ̀ ti o fi nà ọ̀kọ sẹhin, titi o fi run gbogbo awọn ara ilu Ai tútu.
27. Kìki ohun-ọ̀sin ati ikogun ilu na ni Israeli kó fun ara wọn, gẹgẹ bi ọ̀rọ OLUWA ti o palaṣẹ fun Joṣua.
28. Joṣua si kun Ai, o sọ ọ di òkiti lailai, ani ahoro titi di oni-oloni.
29. Ọba Ai li o si so rọ̀ lori igi titi di aṣalẹ: bi õrùn si ti wọ̀, Joṣua paṣẹ ki a sọ okú rẹ̀ kuro lori igi kalẹ, ki a si wọ́ ọ jù si atiwọ̀ ibode ilu na, ki a si kó òkiti nla okuta lé e lori, ti mbẹ nibẹ̀ titi di oni-oloni.
30. Nigbana ni Joṣua tẹ́ pẹpẹ kan fun OLUWA, Ọlọrun Israeli, li òke Ebali,