Yorùbá Bibeli

Tit 2:1-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. ṢUGBỌN iwọ mã sọ ohun ti o yẹ si ẹkọ́ ti o yè kõro:

2. Ki awọn àgba ọkunrin jẹ ẹni iwọntunwọnsin, ẹni-ọ̀wọ, alairekọja, ẹniti o yè kõro ni igbagbọ́, ni ifẹ, ni sũru.

3. Bẹ̃ gẹgẹ ni ki awọn agba obinrin jẹ ẹni-ọ̀wọ ni iwa, ki nwọn má jẹ asọrọ-ẹni-lẹhin, tabi ọmuti, bikoṣe olukọni ni ohun rere;

4. Ki nwọn ki o le tọ́ awọn ọdọmọbirin lati fẹran awọn ọkọ wọn, lati fẹran awọn ọmọ wọn,

5. Lati jẹ alairekọja, mimọ́, òṣiṣẹ́ nile, ẹni rere, awọn ti ntẹriba fun awọn ọkọ wọn, ki ọrọ Ọlọrun ki o máṣe di isọ̀rọ-òdi si.

6. Bẹ̃ gẹgẹ ni ki o gbà awọn ọdọmọkunrin niyanju lati jẹ alairekọja.

7. Ninu ohun gbogbo mã fi ara rẹ hàn li apẹrẹ iṣẹ rere: ninu ẹkọ́ mã fi aiṣebajẹ hàn, ìwa àgba,

8. Ọ̀rọ ti o yè kõro, ti a kò le da lẹbi; ki oju ki o tì ẹniti o nṣòdi, li aini ohun buburu kan lati wi si wa.

9. Gbà awọn ọmọ-ọdọ niyanju lati mã tẹriba fun awọn oluwa wọn, ki nwọn ki o mã ṣe ohun ti o wu wọn ninu ohun gbogbo; ki nwọn ki o má gbó wọn lohùn;

10. Ki nwọn ki o máṣe irẹjẹ, ṣugbọn ki nwọn ki o mã fi iwa otitọ rere gbogbo han; ki nwọn ki o le mã ṣe ẹkọ́ Ọlọrun Olugbala wa li ọṣọ́ ninu ohun gbogbo.

11. Nitori ore-ọfẹ Ọlọrun ti nmu igbala fun gbogbo enia wá ti farahan,