11. Kò si ẹniti oyé yé, kò si ẹniti o nwá Ọlọrun.
12. Gbogbo nwọn li o ti yapa, nwọn jumọ di alailere; kò si ẹniti nṣe rere, kò tilẹ si ẹnikan.
13. Isà okú ti o ṣi silẹ li ọfun wọn; ahọn wọn ni nwọn fi nṣe itanjẹ; oró pamọlẹ mbẹ labẹ ète wọn:
14. Ẹnu ẹniti o kún fun èpe ati fun ọ̀rọ kikoro:
15. Ẹsẹ wọn yara lati ta ẹ̀jẹ silẹ:
16. Iparun ati ipọnju wà li ọ̀na wọn:
17. Ọ̀na alafia ni nwọn kò si mọ̀:
18. Ibẹru Ọlọrun kò si niwaju wọn.
19. Awa si mọ̀ pe ohunkohun ti ofin ba wi, o nwi fun awọn ti o wà labẹ ofin: ki gbogbo ẹnu ki o le pamọ́, ati ki a le mu gbogbo araiye wá sabẹ idajọ Ọlọrun.
20. Nitoripe nipa iṣẹ ofin, a kì yio dá ẹnikẹni lare niwaju rẹ̀: nitori nipa ofin ni ìmọ ẹ̀ṣẹ ti wá.
21. Ṣugbọn nisisiyi a ti fi ododo Ọlọrun hàn laisi ofin, ti a njẹri si nipa ofin ati nipa awọn woli;