Yorùbá Bibeli

Rom 3:10-24 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Kò si ẹniti iṣe olododo, kò si ẹnikan:

11. Kò si ẹniti oyé yé, kò si ẹniti o nwá Ọlọrun.

12. Gbogbo nwọn li o ti yapa, nwọn jumọ di alailere; kò si ẹniti nṣe rere, kò tilẹ si ẹnikan.

13. Isà okú ti o ṣi silẹ li ọfun wọn; ahọn wọn ni nwọn fi nṣe itanjẹ; oró pamọlẹ mbẹ labẹ ète wọn:

14. Ẹnu ẹniti o kún fun èpe ati fun ọ̀rọ kikoro:

15. Ẹsẹ wọn yara lati ta ẹ̀jẹ silẹ:

16. Iparun ati ipọnju wà li ọ̀na wọn:

17. Ọ̀na alafia ni nwọn kò si mọ̀:

18. Ibẹru Ọlọrun kò si niwaju wọn.

19. Awa si mọ̀ pe ohunkohun ti ofin ba wi, o nwi fun awọn ti o wà labẹ ofin: ki gbogbo ẹnu ki o le pamọ́, ati ki a le mu gbogbo araiye wá sabẹ idajọ Ọlọrun.

20. Nitoripe nipa iṣẹ ofin, a kì yio dá ẹnikẹni lare niwaju rẹ̀: nitori nipa ofin ni ìmọ ẹ̀ṣẹ ti wá.

21. Ṣugbọn nisisiyi a ti fi ododo Ọlọrun hàn laisi ofin, ti a njẹri si nipa ofin ati nipa awọn woli;

22. Ani ododo Ọlọrun nipa igbagbọ́ ninu Jesu Kristi, si gbogbo enia, ati lara gbogbo awọn ti o gbagbọ́: nitoriti kò si ìyatọ:

23. Gbogbo enia li o sá ti ṣẹ̀, ti nwọn si kuna ogo Ọlọrun;

24. Awọn ẹniti a ndalare lọfẹ nipa ore-ọfẹ rẹ̀, nipa idande ti o wà ninu Kristi Jesu: