Yorùbá Bibeli

Rom 11:21-32 Yorùbá Bibeli (YCE)

21. Nitori bi Ọlọrun kò ba da ẹ̀ka-iyẹka si, kiyesara ki o máṣe alaida iwọ na si.

22. Nitorina wo ore ati ikannu Ọlọrun: lori awọn ti o ṣubu, ikannu; ṣugbọn lori iwọ, ore, bi iwọ ba duro ninu ore rẹ̀: ki a má ba ke iwọ na kuro.

23. Ati awọn pẹlu, bi nwọn kò ba joko sinu aigbagbọ́, a o lọ́ wọn sinu rẹ̀: nitori Ọlọrun le tún wọn lọ́ sinu rẹ̀.

24. Nitori bi a ti ke iwọ kuro lara igi oróro igbẹ́ nipa ẹda, ti a si lọ́ iwọ sinu igi oróro rere lodi si ti ẹda: melomelo li a o lọ́ awọn wọnyi, ti iṣe ẹka-iyẹka sara igi oróro wọn?

25. Ará, emi kò sá fẹ ki ẹnyin ki o wà li òpe niti ohun ijinlẹ yi, ki ẹnyin má ba ṣe ọlọ́gbọn li oju ara nyin; pe ifọju bá Israeli li apakan, titi kíkún awọn Keferi yio fi de.

26. Bẹ̃li a o si gbà gbogbo Israeli là; gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Ni Sioni li Olugbala yio ti jade wá, yio si yi aiwa-bi-Ọlọrun kuro lọdọ Jakọbu:

27. Eyi si ni majẹmu mi fun wọn, nigbati emi o mu ẹ̀ṣẹ wọn kuro.

28. Nipa ti ihinrere, ọtá ni nwọn nitori nyin: bi o si ṣe ti iyanfẹ ni, olufẹ ni nwọn nitori ti awọn baba.

29. Nitori ailábámọ̀ li ẹ̀bun ati ipe Ọlọrun.

30. Nitori gẹgẹ bi ẹnyin kò ti gbà Ọlọrun gbọ́ ri, ṣugbọn nisisiyi ti ẹnyin ri ãnu gbà nipa aigbagbọ́ wọn:

31. Gẹgẹ bẹ̃li awọn wọnyi ti o ṣe aigbọran nisisiyi, ki awọn pẹlu ba le ri ãnu gbà nipa ãnu ti a fi hàn nyin.

32. Nitori Ọlọrun sé gbogbo wọn mọ pọ̀ sinu aigbagbọ́, ki o le ṣãnu fun gbogbo wọn.