Yorùbá Bibeli

O. Daf 26:6-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

6. Emi o wẹ̀ ọwọ mi li ailẹṣẹ: bẹ̃li emi o si yi pẹpẹ rẹ ká, Oluwa.

7. Ki emi ki o le fi ohùn ọpẹ rò kalẹ, ti emi o si ma sọ̀rọ gbogbo iṣẹ iyanu rẹ.

8. Oluwa, emi ti nfẹ ibujoko ile rẹ, ibi agọ ọlá rẹ.

9. Máṣe kó ọkàn mi pọ̀ pẹlu awọn ẹlẹṣẹ, tabi ẹmi mi pẹlu awọn enia-ẹ̀jẹ.

10. Li ọwọ ẹniti ìwa-ìka mbẹ, ọwọ ọtún wọn si kún fun abẹtẹlẹ.