Yorùbá Bibeli

O. Daf 26:1-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. ṢE idajọ mi, Oluwa; nitori ti mo ti nrìn ninu ìwa titọ mi; emi ti gbẹkẹle Oluwa pẹlu; njẹ ẹsẹ mi kì yio yẹ̀.

2. Wadi mi, Oluwa, ki o si ridi mi; dán inu mi ati ọkàn mi wò.

3. Nitoriti iṣeun-ifẹ rẹ mbẹ niwaju mi: emi si ti nrìn ninu otitọ rẹ.

4. Emi kò ba ẹni asan joko, bẹ̃li emi kì yio ba awọn alayidayida wọle.

5. Emi ti korira ijọ awọn oluṣe-buburu; emi kì yio si ba awọn enia buburu joko.

6. Emi o wẹ̀ ọwọ mi li ailẹṣẹ: bẹ̃li emi o si yi pẹpẹ rẹ ká, Oluwa.

7. Ki emi ki o le fi ohùn ọpẹ rò kalẹ, ti emi o si ma sọ̀rọ gbogbo iṣẹ iyanu rẹ.

8. Oluwa, emi ti nfẹ ibujoko ile rẹ, ibi agọ ọlá rẹ.