Yorùbá Bibeli

O. Daf 133:1-3 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. KIYESI i, o ti dara o si ti dùn to fun awọn ará lati ma jumọ gbe ni irẹpọ̀.

2. O dabi ororo ikunra iyebiye li ori, ti o ṣàn de irungbọn, ani irungbọn Aaroni: ti o si ṣàn si eti aṣọ rẹ̀;

3. Bi ìri Hermoni ti o ṣàn sori òke Sioni: nitori nibẹ ni Oluwa gbe paṣẹ ibukún, ani ìye lailai.