Yorùbá Bibeli

O. Daf 118:21-25 Yorùbá Bibeli (YCE)

21. Emi o yìn ọ: nitori ti iwọ gbohùn mi, iwọ si di igbala mi.

22. Okuta ti awọn ọ̀mọle kọ̀ silẹ li o di pataki igun ile.

23. Lati ọdọ Oluwa li eyi: o ṣe iyanu li oju wa.

24. Eyi li ọjọ ti Oluwa da: awa o ma yọ̀, inu wa yio si ma dùn ninu rẹ̀.

25. Ṣe igbala nisisiyi, emi mbẹ ọ, Oluwa: Oluwa emi bẹ ọ, rán alafia.