Yorùbá Bibeli

Mat 9:20-38 Yorùbá Bibeli (YCE)

20. Si kiyesi i, obinrin kan ti o ni isun ẹ̀jẹ li ọdún mejila, o wá lẹhin rẹ̀, o fi ọwọ́ kàn iṣẹti aṣọ rẹ̀.

21. Nitori o wi ninu ara rẹ̀ pe, Bi mo ba sá le fi ọwọ́ kàn aṣọ rẹ̀, ara mi ó da.

22. Nigbati Jesu si yi ara rẹ̀ pada ti o ri i, o wipe, Ọmọbinrin, tújuka, igbagbọ́ rẹ mu ọ larada. A si mu obinrin na larada ni wakati kanna.

23. Nigbati Jesu si de ile ijoye na, o ba awọn afunfere ati ọ̀pọ enia npariwo.

24. O wi fun wọn pe, Bìla; nitori ọmọbinrin na ko kú, sisùn li o sùn. Nwọn si fi rín ẹrin ẹlẹyà.

25. Ṣugbọn nigbati a si ṣe ti awọn enia jade, o bọ sile, o si fà ọmọbinrin na li ọwọ́ soke; bẹ̃li ọmọbinrin na si dide.

26. Okikí si kàn ká gbogbo ilẹ nã.

27. Nigbati Jesu si jade nibẹ̀, awọn ọkunrin afọju meji tọ̀ ọ lẹhin, nwọn kigbe soke wipe, Iwọ ọmọ Dafidi, ṣãnu fun wa.

28. Nigbati o si wọ̀ ile, awọn afọju na tọ̀ ọ wá: Jesu bi wọn pe, Ẹnyin gbagbọ́ pe mo le ṣe eyi? Nwọn wi fun u pe, Iwọ le ṣe e, Oluwa.

29. Nigbana li o fi ọwọ́ bà wọn li oju, o wipe, Ki o ri fun nyin, gẹgẹ bi igbagbọ́ nyin.

30. Oju wọn si là; Jesu si kìlọ fun wọn gidigidi, wipe, Kiyesi i, ki ẹ máṣe jẹ ki ẹnikan ki o mọ̀.

31. Ṣugbọn nigbati nwọn lọ, nwọn ròhin rẹ̀ yi gbogbo ilu na ká.

32. Bi nwọn ti njade lọ, wò o, nwọn mu ọkunrin odi kan tọ̀ ọ wá, ti o li ẹmi èṣu.

33. Nigbati a lé ẹmi èṣu na jade, odi si fọhùn; ẹnu si yà awọn enia, nwọn wipe, A ko ri irú eyi ri ni Israeli.

34. Ṣugbọn awọn Farisi wipe, agbara olori awọn ẹmi èṣu li o fi lé awọn ẹmi èṣu jade.

35. Jesu si rìn si gbogbo ilu-nla ati iletò, o nkọni ninu sinagogu wọn, o si nwãsu ihinrere ijọba, o si nṣe iwòsan arun ati gbogbo àisan li ara awọn enia.

36. Ṣugbọn nigbati o ri ọ̀pọ enia, ãnu wọn ṣe e, nitoriti ãrẹ̀ mu wọn, nwọn, si tuká kiri bi awọn agutan ti ko li oluṣọ.

37. Nigbana li o wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Lõtọ ni ikorè pọ̀, ṣugbọn awọn alagbaṣe ko to nkan;

38. Nitorina ẹ gbadura si Oluwa ikorè ki o le rán awọn alagbaṣe sinu ikorè rẹ̀.