Yorùbá Bibeli

Mat 5:11-25 Yorùbá Bibeli (YCE)

11. Alabukún-fun li ẹnyin, nigbati nwọn ba nkẹgan nyin, ti nwọn ba nṣe inunibini si nyin, ti nwọn ba nfi eke sọ̀rọ buburu gbogbo si nyin nitori emi.

12. Ẹ mã yọ̀, ki ẹnyin ki o si fò fun ayọ̀: nitori ère nyin pọ̀ li ọrun: bẹ̃ni nwọn sá ṣe inunibini si awọn wolĩ ti o ti mbẹ ṣaju nyin.

13. Ẹnyin ni iyọ̀ aiye: ṣugbọn bi iyọ̀ ba di obu, kini a o fi mu u dùn? kò nilari mọ́, bikoṣepe a dà a nù, ki o si di itẹmọlẹ li atẹlẹsẹ enia.

14. Ẹnyin ni imọlẹ aiye. Ilu ti a tẹ̀do lori òke ko le farasin.

15. Bẹ̃ni a kì itàn fitila tan, ki a si fi i sabẹ òṣuwọn; bikoṣe lori ọpá fitila, a si fi imọlẹ fun gbogbo ẹniti mbẹ ninu ile.

16. Ẹ jẹ ki imọlẹ nyin ki o mọlẹ tobẹ̃ niwaju enia, ki nwọn ki o le mã ri iṣẹ rere nyin, ki nwọn ki o le ma yìn Baba nyin ti mbẹ li ọrun logo.

17. Ẹ máṣe rò pe, emi wá lati pa ofin tabi awọn wolĩ run: emi kò wá lati parun, bikoṣe lati muṣẹ.

18. Lõtọ ni mo sá wi fun nyin, Titi ọrun on aiye yio fi kọja lọ, ohun kikini kan ninu ofin kì yio kọja, bi o ti wù ki o ri, titi gbogbo rẹ̀ yio fi ṣẹ.

19. Ẹnikẹni ti o ba rú ọkan kikini ninu ofin wọnyi, ti o ba si nkọ́ awọn enia bẹ̃, on na li a o pè ni kikini ni ijọba ọrun: ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba nṣe wọn ti o ba si nkọ́ wọn, on na li a o pè ni ẹni-nla ni ijọba ọrun.

20. Nitori mo wi fun nyin, bikoṣepe ododo nyin ba kọja ododo awọn akọwe ati ti awọn Farisi, ẹnyin kì yio le de ilẹ-ọba ọrun bi o ti wù ki o ri.

21. Ẹnyin ti gbọ́ bi a ti wi fun awọn ará igbãni pe, Iwọ ko gbọdọ pania; ẹnikẹni ti o ba pania yio wà li ewu idajọ.

22. Ṣugbọn emi wi fun nyin, ẹnikẹni ti o binu si arakunrin rẹ̀ lasan, yio wà li ewu idajọ; ati ẹnikẹni ti o ba wi fun arakunrin rẹ̀ pe, Alainilari, yio wà li ewu ajọ awọn igbimọ; ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba wipe, Iwọ aṣiwere, yio wà li ewu iná ọrun apadi.

23. Nitorina bi iwọ ba nmu ẹ̀bun rẹ wá si ibi pẹpẹ, bi iwọ ba si ranti nibẹ pe, arakunrin rẹ li ohun kan ninu si ọ,

24. Fi ẹ̀bun rẹ silẹ nibẹ̀ niwaju pẹpẹ, si lọ, kọ́ ba arakunrin rẹ làja na, nigbana ni ki o to wá ibùn ẹ̀bun rẹ.

25. Ba ọtà rẹ rẹ́ kánkan nigbati iwọ wà li ọ̀na pẹlu rẹ̀; ki ọtá rẹ ki o má ba fi ọ le onidajọ lọwọ, onidajọ a si fi ọ le ẹ̀ṣọ lọwọ, a si gbè ọ sọ sinu tubu.