Yorùbá Bibeli

Mat 28:1-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. LI opin ọjọ isimi, bi ilẹ ọjọ kini ọ̀sẹ ti bèrẹ si imọ́, Maria Magdalene ati Maria keji wá lati wò ibojì na.

2. Si wò o, ìṣẹlẹ nla ṣẹ̀: nitori angẹli Oluwa ti ọrun sọkalẹ wá, o si yi okuta na kuro, o si joko le e.

3. Oju rẹ̀ dabi manamana, aṣọ rẹ̀ si fún bi ẹ̀gbọn owu:

4. Nitori ẹ̀ru rẹ̀ awọn oluṣọ warìri, nwọn si dabi okú.

5. Angẹli na si dahùn, o si wi fun awọn obinrin na pe, Ẹ má bẹ̀ru: nitori emi mọ̀ pe ẹnyin nwá Jesu, ti a ti kàn mọ agbelebu.

6. Kò si nihinyi: nitori o ti jinde gẹgẹ bi o ti wi. Wá, ẹ wò ibiti Oluwa ti dubulẹ si.

7. Ẹ si yara lọ isọ fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, o ti jinde kuro ninu okú; wo o, ó ṣãju nyin lọ si Galili; nibẹ̀ li ẹnyin o gbé ri i: wo o, mo ti sọ fun nyin.

8. Nwọn si fi ibẹru pẹlu ayọ̀ nla yara lọ kuro ni ibojì; nwọn si saré lọ iròhin fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀.

9. Bi nwọn si ti nlọ isọ fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, wo o, Jesu pade wọn, o wipe, Alafia. Nwọn si wá, nwọn si gbá a li ẹsẹ mu, nwọn si tẹriba fun u.

10. Nigbana ni Jesu wi fun wọn pe, Ẹ má bẹ̀ru: ẹ lọ isọ fun awọn arakunrin mi pe, ki nwọn ki o lọ si Galili, nibẹ̀ ni nwọn o gbé ri mi.

11. Njẹ bi nwọn ti nlọ, wo o, ninu awọn olusọ wá si ilu, nwọn rohin gbogbo nkan wọnyi ti o ṣe fun awọn olori alufa.

12. Nigbati awọn pẹlu awọn agbàgba pejọ, ti nwọn si gbìmọ, nwọn fi ọ̀pọ owo fun awọn ọmọ-ogun na,

13. Nwọn wi fun wọn pe, Ẹ wipe, Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wá li oru, nwọn si ji i gbé lọ nigbati awa sùn.

14. Bi eyi ba de etí Bãlẹ, awa o yi i li ọkàn pada, a o si gbà nyin silẹ.