Yorùbá Bibeli

Mat 15:16-27 Yorùbá Bibeli (YCE)

16. Jesu si wipe, Ẹnyin pẹlu wà li aimoye sibẹ?

17. Ẹnyin ko mọ̀ pe, ohunkohun ti o ba bọ si ẹnu lọ si inu, a si yà a jade?

18. Ṣugbọn nkan wọnni ti o ti ẹnu jade, inu ọkàn li o ti wá; nwọn a si sọ enia di alaimọ́.

19. Nitori lati inu ọkàn ni iro buburu ti ijade wá, ipania, panṣaga, àgbere, olè, ẹ̀rí èké ati ọ̀rọ buburu;

20. Ohun wọnyi ni isọ enia di alaimọ́: ṣugbọn ki a jẹun li aiwẹwọ́ kò sọ enia di alaimọ́.

21. Jesu si ti ibẹ̀ kuro, o si lọ si àgbegbe Tire on Sidoni.

22. Si wò o, obinrin kan ara Kenaani ti ẹkùn na wá, o si kigbe pè e, wipe, Oluwa, iwọ ọmọ Dafidi, ṣãnu fun mi; ọmọbinrin mi li ẹmi èṣu ndá lóró gidigidi.

23. Ṣugbọn kò si dá a lohùn ọrọ kan. Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wá, nwọn bẹ̀ ẹ, wipe, Rán a lọ kuro, nitoriti o nkigbe tọ̀ wá lẹhin.

24. Ṣugbọn o dahùn wipe, A kò rán mi, bikoṣe si awọn agutan ile Israeli ti o nù.

25. Nigbana li o wá, o si tẹriba fun u, wipe, Oluwa, ràn mi lọwọ.

26. Ṣugbọn o dahùn, wipe, Ko tọ́ ki a mu akara awọn ọmọ, ki a fi i fun ajá.

27. O si wipe, Bẹni, Oluwa: awọn ajá a ma jẹ ninu ẹrún ti o ti ori tabili oluwa wọn bọ́ silẹ.