Yorùbá Bibeli

Mak 9:8-17 Yorùbá Bibeli (YCE)

8. Lojiji, nigbati nwọn si wò yika, nwọn ko si ri ẹnikan mọ́, bikoṣe Jesu nikan pẹlu ara wọn.

9. Bi nwọn si ti nti ori òke sọkalẹ, o paṣẹ fun wọn pe, ki nwọn ki o máṣe sọ ohun ti nwọn ri fun ẹnikan, bikoṣe igbati Ọmọ-enia ba ti jinde kuro ninu okú.

10. Nwọn si fi ọ̀rọ na pamọ́ sinu ara wọn, nwọn si mbi ara wọn lẽre, kili ajinde kuro ninu okú iba jẹ.

11. Nwọn si bi i lẽre, wipe, Ẽṣe ti awọn akọwe fi nwipe, Elijah ni yio tètekọ de?

12. O si dahùn o si wi fun wọn pe, Lõtọ, ni Elijah yio tètekọ, de, yio si mu nkan gbogbo pada si ipò; ati gẹgẹ bi a ti kọwe rẹ̀ nipa ti Ọmọ-enia pe, ko le ṣaima jìya ohun pipọ, ati pe a o si kọ̀ ọ silẹ.

13. Ṣugbọn mo wi fun nyin pe, Elijah ti de na, nwọn si ti ṣe ohunkohun ti o wù wọn si i, gẹgẹ bi a ti kọwe nipa rẹ̀.

14. Nigbati nwọn si de ọdọ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, nwọn ri ijọ enia pipọ lọdọ wọn, awọn akọwe si mbi wọn lẽre ọ̀ran.

15. Lọgan nigbati gbogbo enia si ri i, ẹnu si yà wọn gidigidi, nwọn si sare tọ ọ nwọn nki i.

16. O si bi awọn akọwe, wipe, Kili ẹnyin mbère lọwọ wọn?

17. Ọkan ninu ijọ enia na si dahùn, wipe, Olukọni, mo mu ọmọ mi ti o ni odi, ẹmi tọ̀ ọ wá;