Yorùbá Bibeli

Mak 9:40-50 Yorùbá Bibeli (YCE)

40. Nitori ẹniti ko ba kọ oju ija si wa, o wà ni iha tiwa.

41. Nitori ẹnikẹni ti o ba fi ago omi fun nyin mu li orukọ mi, nitoriti ẹnyin jẹ ti Kristi, lõtọ ni mo wi fun nyin, on kì yio padanù ère rẹ̀ bi o ti wù ki o ri.

42. Ẹnikẹni ti o ba si mu ki ọkan ninu awọn kekeke wọnyi ti o gbà mi gbọ́ kọsẹ̀, o sàn fun u ki a so ọlọ nla mọ́ ọ li ọrùn, ki a si sọ ọ sinu omi okun.

43. Bi ọwọ́ rẹ, ba si mu ọ kọsẹ̀, ke e kuro: o sàn fun ọ ki o ṣe akewọ lọ si ibi iye, jù ki o li ọwọ mejeji ki o lọ si ọrun apadi, sinu iná ajõku,

44. Nibiti kòkoro wọn ki ikú, ti iná na kì si ikú.

45. Bi ẹsẹ rẹ ba si mu ọ kọsè, ke e kuro: o sàn fun ọ ki o ṣe akesẹ lọ si ibi ìye, jù ki o li ẹsẹ mejeji ki a gbé ọ sọ si ọrun apadi, sinu iná ajõku,

46. Nibiti kòkoro wọn ki ikú, ti iná na ki si ikú.

47. Bi oju rẹ ba si mu ọ kọsẹ̀, yọ ọ jade: o sàn fun ọ ki o lọ si ijọba Ọlọrun li olojukan, jù ki o li oju mejeji, ki a gbé ọ sọ sinu iná ọrun apadi,

48. Nibiti kòkoro wọn ki ikú, ti iná na ki si ikú.

49. Nitoripe olukukuku li a o fi iná dùn, ati gbogbo ẹbọ li a o si fi iyọ̀ dùn.

50. Iyọ̀ dara: ṣugbọn bi iyọ̀ ba sọ agbara rẹ̀ nù, kili ẹ o fi mu u dùn? Ẹ ni iyọ̀ ninu ara nyin, ki ẹ si ma wà li alafia lãrin ara nyin.