Yorùbá Bibeli

Mak 15:33-47 Yorùbá Bibeli (YCE)

33. Nigbati o di wakati kẹfa, òkunkun si ṣú bò gbogbo ilẹ titi o fi di wakati kẹsan.

34. Ni wakati kẹsan ni Jesu si kigbe soke li ohùn rara, wipe, Eloi, Eloi, lama sabaktani? itumọ eyi ti ijẹ, Ọlọrun mi, Ọlọrun mi, ẽṣe ti iwọ fi kọ̀ mi silẹ?

35. Nigbati awọn kan ninu awọn ti o duro nibẹ̀ gbọ́ eyi, nwọn wipe, Wò o, o npè Elijah.

36. Ẹnikan si sare, o fi sponge bọ ọti kikan, o fi le ori ọpá iyè, o fifun u mu, wipe, Ẹ jọwọ rẹ̀ si; ẹ jẹ ki a ma wò bi Elijah yio wá gbé e sọkalẹ.

37. Jesu si kigbe soke li ohùn rara, o jọwọ ẹmi rẹ̀ lọwọ.

38. Aṣọ ikele tẹmpili si ya si meji lati oke de isalẹ.

39. Nigbati balogun ọrún, ti o duro niha ọdọ rẹ̀ ri ti o kigbe soke bayi, ti o si jọwọ ẹmi rẹ̀ lọwọ, o wipe, Lõtọ Ọmọ Ọlọrun li ọkunrin yi iṣe.

40. Awọn obinrin pẹlu si wà li òkere nwọn nwò: ninu awọn ẹniti Maria Magdalene wà, ati Maria iya Jakọbu kekere, ati ti Jose ati Salome;

41. (Awọn ẹniti, nigbati o wà ni Galili, ti nwọn ntọ̀ ọ lẹhin, ti nwọn si nṣe iranṣẹ fun u;) ati ọ̀pọ obinrin miran pẹlu, ti o ba a goke wá si Jerusalemu.

42. Nigbati alẹ si lẹ, nitoriti iṣe ọjọ ipalẹmọ, eyini ni, ọjọ ti o ṣiwaju ọjọ isimi,

43. Josefu ara Arimatea, ọlọlá ìgbimọ, ẹniti on tikalarẹ̀ pẹlu nreti ijọba Ọlọrun, o wá, o si wọle tọ̀ Pilatu lọ laifòya, o si tọrọ okú Jesu.

44. Ẹnu si yà Pilatu gidigidi, bi o ti kú na: o si pè balogun ọrún, o bi i lẽre bi igba ti o ti kú ti pẹ diẹ.

45. Nigbati o si mọ̀ lati ọdọ balọgun ọrún na, o si fi okú na fun Josefu.

46. O si rà aṣọ ọgbọ wá, o si sọ̀ ọ kalẹ, o si fi aṣọ ọgbọ na dì i, o si tẹ́ ẹ sinu ibojì ti a gbẹ́ ninu apata, o si yi okuta kan di ẹnu-ọ̀na ibojì na.

47. Ati Maria Magdalene, ati Maria iya Jose, ri ibi ti a gbé tẹ́ ẹ si.