Yorùbá Bibeli

Mak 1:22-32 Yorùbá Bibeli (YCE)

22. Ẹnu si yà wọn si ẹkọ́ rẹ̀: nitoriti o nkọ́ wọn bi ẹniti o li aṣẹ, kì isi ṣe bí awọn akọwe.

23. Ọkunrin kan si wà ninu sinagogu wọn, ti o li ẹmi aimọ́; o si kigbe soke.

24. O wipe, Jọwọ wa jẹ; kini ṣe tawa tirẹ, Jesu ara Nasareti? iwọ wá lati pa wa run? emi mọ̀ ẹniti iwọ ṣe, Ẹni-Mimọ́ Ọlọrun.

25. Jesu si ba a wi, o wipe, Pa ẹnu rẹ mọ́, ki o si jade kuro lara rẹ̀.

26. Nigbati ẹmi aimọ́ na si gbé e ṣanlẹ, o ke li ohùn rara, o si jade kuro lara rẹ̀.

27. Hà si ṣe gbogbo wọn, tobẹ̃ ti nwọn fi mbi ara wọn lẽre, wipe, Kili eyi? ẹkọ́ titun li eyi? nitoriti o fi agbara paṣẹ fun awọn ẹmi aimọ́, nwọn si gbọ́ tirẹ̀.

28. Lojukanna okikí rẹ̀ si kàn yi gbogbo ẹkùn Galili ká.

29. Nigbati nwọn si jade kuro ninu sinagogu, lojukanna nwọn wọ̀ ile Simoni ati Anderu, pẹlu Jakọbu ati Johanu.

30. Iya aya Simoni si dubulẹ aìsan ibà, nwọn si sọ ọ̀ran rẹ̀ fun u.

31. O si wá, o fà a lọwọ, o si gbé e dide; lojukanna ibà na si fi i silẹ, o si nṣe iranṣẹ fun wọn.

32. Nigbati o di aṣalẹ, ti õrun wọ̀, nwọn gbe gbogbo awọn alaìsan, ati awọn ti o li ẹmi i èṣu tọ̀ ọ wá.