Yorùbá Bibeli

Mak 1:18-27 Yorùbá Bibeli (YCE)

18. Lojukanna nwọn si fi àwọn wọn silẹ, nwọn si tọ̀ ọ lẹhin.

19. Bi o si ti lọ siwaju diẹ, o ri Jakọbu ọmọ Sebede, ati Johanu arakunrin rẹ̀, nwọn wà ninu ọkọ̀, nwọn ndí àwọn wọn.

20. Lojukanna o si pè wọn: nwọn si fi Sebede baba wọn silẹ ninu ọkọ̀ pẹlu awọn alagbaṣe, nwọn si tọ̀ ọ lẹhin.

21. Nwọn si lọ si Kapernaumu; lojukanna o si wọ̀ inu sinagogu li ọjọ, isimi, o si nkọ́ni.

22. Ẹnu si yà wọn si ẹkọ́ rẹ̀: nitoriti o nkọ́ wọn bi ẹniti o li aṣẹ, kì isi ṣe bí awọn akọwe.

23. Ọkunrin kan si wà ninu sinagogu wọn, ti o li ẹmi aimọ́; o si kigbe soke.

24. O wipe, Jọwọ wa jẹ; kini ṣe tawa tirẹ, Jesu ara Nasareti? iwọ wá lati pa wa run? emi mọ̀ ẹniti iwọ ṣe, Ẹni-Mimọ́ Ọlọrun.

25. Jesu si ba a wi, o wipe, Pa ẹnu rẹ mọ́, ki o si jade kuro lara rẹ̀.

26. Nigbati ẹmi aimọ́ na si gbé e ṣanlẹ, o ke li ohùn rara, o si jade kuro lara rẹ̀.

27. Hà si ṣe gbogbo wọn, tobẹ̃ ti nwọn fi mbi ara wọn lẽre, wipe, Kili eyi? ẹkọ́ titun li eyi? nitoriti o fi agbara paṣẹ fun awọn ẹmi aimọ́, nwọn si gbọ́ tirẹ̀.