Yorùbá Bibeli

Luk 5:20-30 Yorùbá Bibeli (YCE)

20. Nigbati o si ri igbagbọ́ wọn, o wi fun u pe, Ọkunrin yi, a dari ẹ̀ṣẹ rẹ jì ọ.

21. Awọn akọwe ati awọn Farisi bẹ̀rẹ si igberò, wipe, Tali eleyi ti nsọ ọrọ-odi? Tali o le dari ẹ̀ṣẹ jìni bikoṣe Ọlọrun nikanṣoṣo?

22. Ṣugbọn nigbati Jesu mọ̀ ìro inu wọn, o dahùn o si wi fun wọn pe, Kili ẹnyin nrò ninu ọkàn nyin?

23. Ewo li o ya jù, lati wipe, A dari ẹ̀ṣẹ rẹ jì ọ; tabi lati wipe, Dide ki iwọ ki o si mã rìn?

24. Ṣugbọn ki ẹnyin ki o le mọ̀ pe, Ọmọ-enia li agbara li aiye lati dari ẹ̀ṣẹ jìni, (o wi fun ẹlẹgba na pe,) Mo wi fun ọ, Dide, si gbé akete rẹ, ki o si lọ si ile rẹ.

25. O si dide lọgan niwaju wọn, o gbé ohun ti o dubulẹ le, o si lọ si ile rẹ̀, o nyìn Ọlọrun logo.

26. Ẹnu si yà gbogbo wọn, nwọn si nyìn Ọlọrun logo, ẹ̀ru si bà wọn, nwọn nwipe, Awa ri ohun abàmi loni.

27. Lẹhin nkan wọnyi o jade lọ, o si ri agbowode kan ti a npè ni Lefi, o joko ni bode: o si wi fun u pe, Mã tọ̀ mi lẹhin.

28. O si fi gbogbo nkan silẹ, o dide, o si ntọ̀ ọ lẹhin.

29. Lefi si se àse nla fun u ni ile rẹ̀: ọ̀pọ ijọ awọn agbowode, ati awọn ẹlomiran mbẹ nibẹ̀ ti nwọn ba wọn joko.

30. Ṣugbọn awọn akọwe, ati awọn Farisi nkùn si awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, wipe, Ẽṣe ti ẹnyin fi mbá awọn agbowode ati awọn ẹlẹṣẹ jẹ, ti ẹ mba wọn mu.